Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 6, 2017
OHUN TUNTUN

Abala Tá A Ń Pè Ní “Ẹ̀kọ́ Bíbélì” Ti Yi Pa Dà

Abala Tá A Ń Pè Ní “Ẹ̀kọ́ Bíbélì” Ti Yi Pa Dà

A ti tún abala táa ń pé ní “Ẹ̀kọ́ Bíbélì” ṣe kó lè rọrùn láti rí àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ tí èèyàn ń wá. Díẹ̀ lára àwọn ohun tó ti yí pa dà rèé:

  • Abala tuntun táa pè ní “Ìtàn àti Bíbélì” ní àwọn àkòrí tó dá lórí bí wọ́n ṣe pa Bíbélì mọ́, tí wọ́n túmọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì pín in kiri àti bí àwọn ohun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rí báyìí ṣe fi hàn pé òótọ́ láwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì.

  • Abala tuntun táa pè ní “Àlàáfíà àti Ayọ̀” ṣàlàyé bí Bíbélì á ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú wàhálà ojoojúmọ́ àti bóo ṣe lè láyọ̀ láìka àwọn ìṣòro tó le koko.

  • Abala tuntun táa pè ní “Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Bíbélì” jẹ́ ká mọ bí àwọn ìṣẹ̀dá tó wà láyé ṣe fi hàn pé Bíbélì bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu.

  • A ti tún abala táa ń pè ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ” ṣe kó lè rọrùn láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè lórí oríṣiríṣi àkòrí

  • Abala táa ń pè ní “Ìrànwọ́ fún Tọkọtaya” tẹ́lẹ̀ ló wá di “Ìgbéyàwó àti Ìdílé” báyìí. Abala yìí sọ ohun tó o lè ṣe kó o lè túbọ̀ gbádùn ìgbéyàwó rẹ, ó sì sọ ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ.