Ayọ̀ Ayérayé
Àpéjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2026
A Fẹ́ Kó O Wá
A kì í gba owó ìwọlé • A kì í gbégbá ọrẹ
Àwọn Nǹkan Tá A Máa Gbádùn
Friday: Wàá rí oríṣiríṣi ẹ̀rí látinú Bíbélì táá jẹ́ kó o mọ̀ pé Ọlọ́run àti Jésù ọmọ rẹ̀ fẹ́ kó o máa láyọ̀.
Saturday: A máa ṣàyẹ̀wò ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè, ìyẹn á sì jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè máa láyọ̀ títí láé.
Sunday: Nínú àsọyé tí àkòrí ẹ̀ ní “Ṣé O Ti Rí Ìṣúra Náà?” wàá rí bí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì ṣe ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa láyọ̀.
Fídíò Ìtàn Bíbélì
Ìhìn Rere Látọ̀dọ̀ Jésù: Abala 4 sí 6
Wàá rí bí Jésù ṣe kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, bó ṣe wo àwọn èèyàn sàn àti bó ṣe jí òkú dìde. Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àpéjọ náà la máa wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn abala fídíò tó ń wọni lọ́kàn yìí.
Lọ sórí ìkànnì jw.org kó o lè rí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ yìí, kó o sì wo àwọn fídíò yìí:
Kí La Máa Ń Ṣe Láwọn Àpéjọ Wa?
Wàá rí bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa ń ṣe àwọn àpéjọ wa.
Wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan tá a máa gbádùn ní àpéjọ tọdún yìí.
Báwo ni Jésù ṣe lo àwọn ẹ̀bùn tó ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?
Wo àwọn abala tá a ti mú jáde láwọn àpéjọ tó kọjá.

