JULY 5, 2019
TAIWAN
Wọ́n Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún ṣe Jáde Lédè Chinese
Ní July 5, 2019, a mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde lédè Chinese ní àpéjọ agbègbè kan tá a ṣe ní ìlú Taoyuan lórílẹ̀-èdè Taiwan. Arákùnrin Kenneth Cook tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló mú Bíbélì náà jáde nígbà tó ń sọ àsọyé kan nínú Gbọ̀ngàn National Taiwan Sport University. Àwọn ẹgbẹ̀rún-ún méjìlá, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mẹ́wàá (12,610) ló gbádùn ètò yìí. Àwọn kan gbádùn ẹ̀ nínú gbọ̀ngàn yẹn, wọ́n sì ta àtagbà ẹ̀ sáwọn àpéjọ agbègbè mẹ́rin míì.
Ọdún 1995 ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Chinese, wọ́n sì ṣe é lọ́nà méjì. Wọ́n lo ọ̀nà ìkọ̀wé tó wọ́pọ̀ ní Hong Kong àti Taiwan mu nínú tí àkọ́kọ́, wọ́n sì lo ọ̀nà ìkọ̀wé tá a mú kó túbọ̀ rọrùn tó wọ́pọ̀ ní Ṣáínà, Màléṣíà àti Singapore fún èkejì. Lọ́dún 2001, wọ́n mú odindi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde. Ẹ̀dà méjì ni wọ́n tún fi ṣe, àkọ́kọ́ jẹ́ ọ̀nà ìkọ̀wé tó jẹ́ ti ìbílẹ̀, ìkejì sì jẹ́ ọ̀nà ìkọ̀wé tá a mú kó túbọ̀ rọrùn láti lóye. Nígbà tó dọdún 2004, a tẹ ẹ̀dà kẹta jáde. Ọ̀nà ìkọ̀wé tá a mú kó túbọ̀ rọrùn láti lóye ni wọ́n lò nínú ẹ̀dà yìí, yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún lo ọ̀nà ìkọ̀wé kan tá à ń pè ní Pinyin kí wọ́n lè fi álífábẹ́ẹ̀tì èdè Róòmù kọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan.
Wọ́n wá mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde ní ẹ̀dà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ti èdè ìbílẹ̀ àti èdè tá a mú kó túbọ̀ rọrùn láti lóye ni wọ́n tẹ̀ sínú ìwé àti sórí ẹ̀rọ, nígbà tí ẹ̀dà Pinyin wà lórí ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ™ (ti Watchtower).
Ní gbogbo ayé, àwọn èèyàn tó lé ní bílíọ̀nù kan ló ń sọ èdè Chinese Mandarin. Òun sì ni èdè ìbílẹ̀ táwọn èèyàn ń sọ jù lọ láyé. Ní àfikún sí àwọn tó ń sọ èdè Mandarin, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló wà tó ń sọ àwọn èdè ìbílẹ̀ Chinese míì, wọ́n sì lè ka àwọn ọ̀rọ̀ tá a kọ lọ́nà ìkọ̀wé Chinese. Ní báyìí, àwọn ará wa tó ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó gbòòrò yìí lè fi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe ran ọ̀pọ̀ èèyàn láti mọ Jèhófà, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—1 Tímótì 2:4.