Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn ará ní Siri Láńkà ń dúró de àwọn àlejò ní pápákọ̀ òfuurufú Bandaranaike International Airport.

DECEMBER 21, 2018
SRI LANKA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Àkànṣe Àpéjọ Fúngbà Àkọ́kọ́ ní Siri Láńkà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Àkànṣe Àpéjọ Fúngbà Àkọ́kọ́ ní Siri Láńkà

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wá láti orílẹ̀-èdè méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti wá bá àwọn ará wọn lọ́kùnrin lóbìnrin ní orílẹ̀-èdè Siri Láńkà ṣe àkànṣe àpéjọ. Ìgbà àkọ́kọ́ tírú ẹ̀ máa wáyé nìyẹn ní orílẹ̀-èdè náà. Ìlú Colombo tó jẹ́ olú-ìlú Siri Láńkà ni wọ́n ti ṣe àkànṣe àpéjọ náà, tí ẹṣin ọ̀rọ̀ ẹ̀ jẹ́ “Jẹ́ Onígboyà”! Pápá ìṣeré Sugathadasa National Sports Complex ni wọ́n lò, July 6 sí 8, 2018 ni wọ́n sì ṣe é. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ó lé mọ́kànlélọ́gọ́fà (14,121) ló wá sí àpéjọ náà. Ara àwọn ohun mánigbàgbé tó wáyé níbi àpéjọ náà ni àwọn àsọyé tí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ, àwọn tó ṣèrìbọmi ní àpéjọ yìí ló tíì pọ̀ jù nínú gbogbo àpéjọ tó ti wáyé ní Siri Láńkà, àwọn ará sì fìfẹ́ gba àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) lálejò lọ́nà tó ta yọ.

September 2017 ni wọ́n fi tó àwọn ará ní Siri Láńkà létí pé àkànṣe àpéjọ kan máa wáyé lọ́dún tó tẹ̀ lé e, àtìgbà yẹn ni ètò sì ti bẹ̀rẹ̀. Yàtọ̀ sí gbogbo ètò tí wọ́n ṣe láti gbàlejò àwọn tó máa wá sí àpéjọ náà, pápá ìṣeré tí wọ́n fẹ́ lò nílò àtúnṣe tó pọ̀. Ó máa gba pé kí wọ́n kùn ún, kí wọ́n kó ìdọ̀tí ibẹ̀, kí wọ́n tún àwọn àga tó ti bà jẹ́ ṣe, kí wọ́n sì dí àwọn ihò ojú ọ̀nà. Nígbà tí àpéjọ náà ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wá kọ́wọ́ ti iṣẹ́ àtúnṣe náà. Ẹ̀ṣọ́ kan tiẹ̀ sọ pé ó máa gba àwọn òṣìṣẹ́ pápá ìṣeré náà ní ọdún mẹ́rin láti ṣe ohun táwọn ará wa ṣe láàárín àkókò kúkúrú yẹn.

Yàtọ̀ sí àwọn àsọyé Bíbélì tí wọ́n sọ ní àpéjọ náà, wọ́n mú àwọn àlejò lọ wo oríṣiríṣi ibi, wọ́n sì ṣe àwọn nǹkan lóríṣiríṣi tó jẹ mọ́ àṣà ìbílẹ̀ Siri Láńkà. Àwọn ará ṣe ohun kan tó jẹ́ mánigbàgbé nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, wọ́n jó ijó ìbílẹ̀, wọ́n sì kọrin ìbílẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run.

Ashley Ferdinands tó jẹ́ aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Siri Láńkà sọ pé: “Ohun ńlá ni ètò Ọlọ́run ṣe fáwọn ará wa lórílẹ̀-èdè yìí pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ṣètò pé ká ṣe àkànṣe àpéjọ, àǹfààní ló sì jẹ́ láti gba àwọn ará wa tó pọ̀ lálejò. A mọyì ọ̀pọ̀ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ kí nǹkan lè lọ dáadáa ní àpéjọ yìí. Àmọ́ Baba wa ọ̀run ni gbogbo ọpẹ́ yẹ, torí àtọ̀dọ̀ ẹ̀ ni gbogbo ẹ̀bùn rere ti ń wá.”—Jémíìsì 1:17.

 

Èdè mẹ́rin ni wọ́n fi ṣe àpéjọ náà: Gẹ̀ẹ́sì (lẹ̀ ń wò níbí), Sinhala, Èdè Àwọn Adití lọ́nà ti Siri Láńkà àti èdè Tamil.

Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

Igba ó lé mẹ́tàléláàádọ́rin (273) làwọn tó ṣèrìbọmi ní àpéjọ náà.

Àwọn ará ṣètò pé káwọn oníròyìn wá gba ìsọfúnni ní ẹ̀ka ọ́fíìsì. Àwọn oníròyìn tó wá lé ní ogójì (40), wọ́n sì mú wọn yí ká ẹ̀ka ọ́fíìsì.

Méjì lára iléeṣẹ́ ìròyìn tó tóbi jù ní Siri Láńkà ń fọ̀rọ̀ wá ẹnì kan lẹ́nu wò, ẹni yìí ló ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn oníròyìn ní àpéjọ náà.

Ní January 2018, àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje (700) kóra jọ sílùú Colombo, kí wọ́n lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti múra sílẹ̀ fún àpéjọ náà.

Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ń tún àwọn àga tó ti bà jẹ́ ṣe níbi tí wọ́n ti fẹ́ ṣe àpéjọ náà.

Àwọn ará ṣe ètò mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́ ní ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba nítòsí ìlú Colombo tí wọ́n ti fẹ́ ṣe àpéjọ náà, èyí jẹ́ kí àwọn àlejò tó wá lè mọ àwọn ará tó wà nílùú náà.

Àwọn ará dárà oríṣiríṣi láti jẹ́ káwọn àlejò rí àṣà ìbílẹ̀ Siri Láńkà, irú bí ijó Tamil tí wọ́n ń jó yìí.

Àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ orin “Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: ‘Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n’”.

Àwọn àlejò kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe tíì, wọ́n sì gbádùn ẹ̀.

Nígbà tí àpéjọ náà parí, àwọn àlejò tó wá síbẹ̀ gbé àwọn àkọlé tí wọ́n kọ nǹkan sí sókè láti jẹ́ káwọn ará wọn lọ́kùnrin lóbìnrin mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn.