Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 5, 2019
SOUTH AFRICA

Òjò Àrọ̀ọ̀rọ̀dá àti Omíyalé ní South Africa

Òjò Àrọ̀ọ̀rọ̀dá àti Omíyalé ní South Africa

Òjò tó rinlẹ̀ gan-an rọ̀ lọ́wọ́ ìparí oṣù April 2019 láwọn ibi tó kángun sí ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè South Africa. Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá náà fa omíyalé àti àbàtà láwọn ibì kan ní ìlú Durban àti ní agbègbè KwaZulu-Natal. Ìròyìn fi hàn pé ó kéré tán, àádọ́rin (70) èèyàn ló kú.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní South Africa sọ pé kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó kú tàbí tó fara pa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Àmọ́, ó kéré tán, ilé àwọn ìdílé mọ́kàndínlógún (19) ni omíyalé àti àbàtà náà bà jẹ́. Omíyalé náà tún ba Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ta jẹ́ ó kéré tán.

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ti ṣètò àwọn ará tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ kí wọ́n lè ṣèwádìí bí ilé kọ̀ọ̀kan ṣe bà jẹ́ tó. Láwọn ibi tí ẹ̀mí àwọn ará ti wà nínú ewu, wọ́n ṣètò láti kó wọn lọ síbòmíì.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní yéé ran àwọn ará wa ní South Africa lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń kojú ìṣòro tó le gan-an yìí.—Sáàmù 34:19.