Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SINGAPORE

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́—Singapore

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́—Singapore

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́jọ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Singapore torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ìgbà kejì nìyí tí mẹ́ta lára wọn máa ṣẹ̀wọ̀n torí pé wọn ò yíhùn pa dà lẹ́yìn tí wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n nígbà àkọ́kọ́. Kò sí báwọn ọ̀dọ́ yìí ṣe lè fi ọ̀rọ̀ òfin tọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn torí ìjọba orílẹ̀-èdè Singapore ti sọ pé dandan ni káwọn èèyàn wọṣẹ́ ológun, wọn ò sì gbà pé ẹnikẹ́ni lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun ò gba òun láyè.

Tí ọ̀dọ́kùnrin kan bá ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) lórílẹ̀-èdè Singapore, wọ́n máa ní kó wá wọṣẹ́ ológun. Tó bá kọ̀, torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣe é, wọ́n á fi sí àtìmọ́lé ní àgọ́ àwọn ológun fún nǹkan bí oṣù méjìlá (12). Tó bá ti lo ọjọ́ ẹ̀ pé lẹ́wọ̀n, wọ́n á dá a sílẹ̀. Wọ́n á wá pàṣẹ pé kó wọ aṣọ ológun lójú ẹsẹ̀, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun. Tó bá tún kọ̀ pé òun ò ṣe, wọ́n á ní kó fojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì lè jù ú sẹ́wọ̀n fún nǹkan bí oṣù méjìdínlógún (18). Nítorí náà, ẹ̀ẹ̀mejì làwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun máa ń ṣẹ̀wọ̀n, àpapọ̀ àsìkò tí wọ́n ń lò lẹ́wọ̀n sì máa ń tó ọgbọ̀n (30) oṣù.

Orílẹ̀-Èdè Singapore Ò Gbà Láti Ṣe Ohun Tí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé Ní Kí Wọ́n Ṣe

Ọjọ́ pẹ́ tí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ti ń rọ àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ wọn pé “kí wọ́n má fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun dù wọ́n torí pé ẹ̀tọ́ láti ní èrò tó wuni, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni gbà láyè àti ẹ̀sìn tó wuni ni wọ́n ń tẹ̀ lé, ìyẹn sì bófin mu torí ó wà nínú ìwé Universal Declaration of Human Rights.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Singapore ti wà lábẹ́ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé látọdún 1965, kò fara mọ́ ohun tí àjọ náà sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Nínú lẹ́tà tí òṣìṣẹ́ ìjọba kan lórílẹ̀-èdè Singapore kọ sí Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ní April 24, 2002, ó sọ pé “tí ohun tí ẹnì kan gbà gbọ́ tàbí tó ń ṣe bá ti ta ko [ẹ̀tọ́ láti gbèjà orílẹ̀-èdè], ẹ̀tọ́ tí orílẹ̀-èdè ní láti pèsè ààbò ló gbọ́dọ̀ gbawájú.” Òṣìṣẹ́ náà sojú abẹ níkòó pé, “A ò fara mọ́ ọn pé ibi gbogbo láyé ni àwọn èèyàn ti lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè.”

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

  1. August 16, 2024

    Lápapọ̀, Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun.

  2. April 24, 2002

    Òṣìṣẹ́ ìjọba fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé orílẹ̀-èdè Singapore ò fara mọ́ ọn pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ò gbà á láyè.

  3. February 1995

    Wọ́n túbọ̀ ń ká àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Singapore tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kò, wọ́n sì ń mú wọn.

  4. August 8, 1994

    Ilé Ẹjọ́ Gíga lórílẹ̀-èdè Singapore ò fọwọ́ sí ohun táwa Ẹlẹ́rìí béèrè.

  5. January 12, 1972

    Lẹ́yìn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ìjọba orílẹ̀-èdè Singapore yọ orúkọ wa kúrò.