Kazakhstan
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kazakhstan
-
Iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—17,188
-
Iye àwọn ìjọ—224
-
Iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi—29,488
-
Iye èèyàn tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa wàásù fún—1,178
-
Iye èèyàn—20,140,000
Teymur Akhmedov Lo 441 Ọjọ́ Lẹ́wọ̀n—A Fọ̀rọ̀ Wá Òun àti Mafiza Ìyàwó Rẹ̀ Lẹ́nu Wò
Teymur Akhmedov sọ ohun tójú ẹ̀ rí nígbà tí wọ́n rán an lọ sẹ́wọ̀n ní Kazakhstan. Ó kọ̀ láti ṣe ohun tó máa ba ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ jẹ́, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.
Wọ́n Dá Teymur Akhmedov Sílẹ̀ Torí Pé Ààrẹ Dárí Jì Í
Ààrẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan dárí ji Teymur Akhmedov, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó ti lé lọ́dún kan tó ti wà lẹ́wọ̀n torí pé ó wàásù ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Ìdáríjì náà ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kúrò lọ́rùn rẹ̀.
Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan Jẹ̀bi fún Bó Ṣe Fi Teymur Akhmedov sí Àtìmọ́lé Lọ́nà Àìtọ́
Ẹgbẹ́ kan tó wà lábẹ́ àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè tó máa ń rí sí ẹjọ́ àwọn tí wọ́n fi sí àtìmọ́lè lọ́nà àìtọ́, ìyẹn WGAD, sọ pé ìjọba ilẹ̀ Kazakhstan jẹ̀bi fún bó ṣe fi Teymur Akhmedov sí àtìmọ́lé lọ́nà àìtọ́.
Ìjọba Ní Kí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-èdè Kazakhstan Dáwọ́ Iṣẹ́ Dúró
Ilé ẹjọ́ kan nílùú Almaty ní Kazakhstan ti sọ pé kí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáwọ́ gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe dúró fún oṣù mẹ́ta.
Àwọn Aláṣẹ ní Kazakhstan Fi Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Ń Ṣàìsàn Sẹ́wọ̀n, Wọ́n sì Fòfin Dè é Pé Kò Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn
Teymur Akhmedov ti níyàwó, ó sì ti bímọ mẹ́ta. Àwọn aláṣẹ rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún torí pé ó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìrọwọ́rọsẹ̀ ló ń ṣe é.
Ìjọba Orílẹ̀-èdè Kazakhstan Fi Òmìnira Ẹ̀sìn Du Teymur Akhmedov, Wọ́n sì Dá A Lẹ́bi
Ilé ẹjọ́ kan nílùú Astana rán Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún. Àwọn aláṣẹ ní Kazakhstan ò yéé ṣèdíwọ́ fún àwọn aráàlú tó ń jọ́sìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀.