OCTOBER 10, 2019
JAPAN
Ìjì Líle Tó Ń Jẹ́ Tapah Rọ́ Lu Apá Gúúsù Orílẹ̀-Èdè Japan
Ní September 21 sí 23, 2019, ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Tapah rọ́ lu apá gúúsù orílẹ̀-èdè Japan pẹ̀lú atẹ́gùn àti òjò tó lágbára. Ìjì yìí ò jẹ́ káwọn ọkọ̀ òfúrufú àtàwọn ọkọ̀ ojú irin lè rìn. Kódà, àwọn ilé tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000) ni ìjì náà ba iná mànàmáná wọn jẹ́. Ní ìlú Okinawa àti Kyushu, àwọn tó ju àádọ́ta (50) lọ ló fara pa.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì Japan ròyìn pé àwọn akéde márùn-ún ló fara pa, wọ́n sì ní láti gbé arábìnrin kan lára wọn lọ sílé ìwòsàn. Yàtọ̀ síyẹn, ilé àwọn arákùnrin wa tó bà jẹ́ lé ní àádọ́ta (50). Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù àti àwọn arákùnrin tó tóótun ti ń bójú tó ohun táwọn ará yìí nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Ẹ̀ka ọ́fíìsì Japan á máa báa lọ láti ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí ìjì yìí bà jẹ́, wọ́n á sì máa pèsè ìrànwọ́ táwọn ará nílò.
Àdúrà wa ni pé kí àwọn ará wa ní Japan máa bá a lọ láti gbára lé Jèhófà, Ọlọ́run ìtùnú ní àkókò wàhálà yìí.—Sáàmù 94:19.