MAY 26, 2020
ÍTÁLÌ
A Fọ̀rọ̀ Wá Dókítà Kan Lẹ́nu Wò Lórílẹ̀-Èdè Ítálì
Dókítà ni Arákùnrin Giandomenico Gullà, ẹ̀ka tó ń bójú tó àwọn tó nílò ìtọ́jú pàjáwìrì ló ti ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ìwòsàn Erba, tó wà nílùú Como, lórílẹ̀-èdè Ítálì. Ojú ẹ̀ ti rí màbo lórí ọ̀rọ̀ àrùn corona tó ń jà ràn-ìn yìí. Àmọ́, àwọn ohun tí arákùnrin wa gbà gbọ́ ń mú kí ọkàn ẹ̀ balẹ̀, ìyẹn ló sì ń jẹ́ kó lè máa tu àwọn míì nínú. (2 Kọ́ríńtì 1:4) A rí ẹ̀rí èyí nínú ohun tó sọ nígbà tí Ẹ̀ka Tó Ń Gbéròyìn Jáde ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Ítálì fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò.
Díẹ̀ lára ohun tí Arákùnrin Gullà sọ nígbà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà ló wà nísàlẹ̀ yìí, àmọ́ a ti ṣe ṣàtúnṣe díẹ̀ sọ́rọ̀ ẹ̀ kí ohun tó sọ lè ṣe kedere.
Àwọn nǹkan wo lẹ̀ ń dojú kọ lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn yìí?
Giandomenico Gullà: Nílé ìwòsàn tí mo ti ń ṣiṣẹ́, ṣàdédé ni gbogbo nǹkan yí pa dà, àfi bí àlá. Wọ́n ṣe àwọn àtúntò kan nílé ìwòsàn náà, kí wọ́n lè ya ẹ̀ka táá máa bójú tó àwọn tó ní àrùn corona sọ́tọ̀. Ó bani nínú jẹ́ pé ṣe ni wọ́n máa ń ya àwọn tó ní àrùn yìí sọ́tọ̀, àwọn tó wà nínú ìdílé wọn, àwọn ìbátan wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn ò sì ní lè sún mọ́ wọn. Torí náà, mo máa ń fi fóònù pe àwọn tó wà nínú ìdílé wọn, kí n lè sọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún wọn. Ní òru ọjọ́ kan, mo ní láti pe ọmọ kan, kí n sì sọ fún un pé bàbá ẹ̀ ò ní pẹ́ kú. Torí náà, mo fi fídíò orí íńtánẹ́ẹ̀tì pè é kó lè rí bàbá ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá náà ò mọ nǹkan kan mọ́. Àkókò yẹn ò dẹrùn rárá.
Báwo ni àwọn nǹkan tẹ́ ẹ mọ̀ nínú Bíbélì ṣe ń tù yín nínú?
Giandomenico Gullà: Mo máa ń rí i pé àwọn kan lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn, àmọ́ ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì ò jẹ́ kí èmi máa ní ẹ̀dùn ọkàn. Ó ti wá túbọ̀ ṣe kedere sí mi pé Jèhófà ti múra wa sílẹ̀ de àkókò tó le koko yìí. Ní tèmi, mo mọ̀ pé àjàkálẹ̀ àrùn yìí jẹ́ ẹ̀rí pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ń ṣẹ, ìyẹn ni ò jẹ́ kí n máa dààmú jù. Ní báyìí, ìgbàgbọ́ mi ti túbọ̀ lágbára.
Báwo ni ìtùnú tẹ́ ẹ̀ ń rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà ṣe ń jẹ́ kẹ́ ẹ lè máa tu àwọn míì nínú?
Giandomenico Gullà: Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ lọ́nà tó lágbára gan-an. Ó ń ràn mí lọ́wọ́ nínú ìdílé mi àti lẹ́nu iṣẹ́, ó sì ń jẹ́ kí n lè ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó wà nínú ìṣòro torí àjàkálẹ̀ àrùn.
Ẹ jọ̀ọ́ ẹ ṣàlàyé fún wa bí Jèhófà ṣe ń ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè máa tu ìdílé yín nínú
Giandomenico Gullà: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń pẹ́ níbi iṣẹ́ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, mo máa ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè rí i pé èmi àti ìdílé mi jọ ń sin Jèhófà pa pọ̀. Mo ti wá rí i pé ohun tí mò ń ṣe yìí ti túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ ìyàwó mi lókun. A ti túbọ̀ sún mọ́ra. Bákan náà, ìjọsìn ìdílé tá à ń ṣe ń tu ọmọ wa obìnrin tó ń jẹ́ Ginevra nínú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọdé ṣì ni, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa pé ọmọ ọdún mẹ́ta ni, òun náà mọ̀ pé nǹkan ti yí pa dà, àwọn ọ̀rọ̀ tó sì máa ń sọ máa ń jẹ́ ká rí i pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ò múnú ẹ̀ dùn. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń sọ pé: ‘Mi ò fẹ́ kí dádì lọ sí ibiṣẹ́ torí àrùn corona,’ àbí kó sọ pé ‘Ẹ̀rù ń bà mí pé dádì lè má pa dà dé.’ Ká lè fi í lọ́kàn balẹ̀, a máa ń jẹ́ kó gbọ́ àwọn orin wa tó máa ń jáde nínú Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW, tó bá sì ti ń gbọ́ ọ, kò ní pẹ́ táá fi máa rẹ́rìn-ín.
Ṣé ẹ lè sọ fún wa bẹ́ ẹ ṣe tu ọ̀kan lára àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ nínú?
Giandomenico Gullà: Ẹnu àìpẹ́ yìí ni ọ̀kan lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọdún mélòó kan sẹ́yìn ni mo pàdé ẹ̀ nílé ìwòsàn tí mo ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀, a sì jọ sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì. Ṣáájú kí àrùn corona tó bẹ̀rẹ̀ sí í jà ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ. Ní báyìí, fídíò orí íńtánẹ́ẹ̀tì la fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, àwọn ìgbà míì sì wà tá a máa ń ṣe é lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Ó jọ mí lójú gan-an nígbà tó sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ fún mi, ó sọ pé: “Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́ yìí ti jẹ́ kí ayé mi dáa sí i. Ó ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀. Mo ti mọ ìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn sáyé, mo sì ti mọ ìdí tí àjàkálẹ̀ àrùn fi ń ṣẹlẹ̀. Ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́ ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi lágbára, èyí jẹ́ kí n lè fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí n sì gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.”
Báwo lẹ ṣe tu àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ yín nínú?
Giandomenico Gullà: Ó ṣeni láàánú pé arábìnrin kan ní ìjọ wa [Arábìnrin Daniela Sgreva] kó àrùn corona, wọ́n sì fẹ́ gbé e wá sílé ìwòsàn tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Mo wá pe àwọn arákùnrin méjì tó ní ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbé aláìsàn, a sì jọ sọ bí wọ́n ṣe máa gbé e wá. Àwọn arákùnrin náà rìnrìn àjo àádọ́ta (50) kìlómítà kí wọ́n lè lọ gbé e wá. Inú arábìnrin yìí dùn gan-an nígbà tó rí wọn! Nígbà tí wọ́n gbé e délé ìwòsàn wa, ara tù ú bó ṣe rí wa tá a wá pàdé ẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń bójú tó àwọn tó nílò ìtọ́jú pàjáwìrì, bo tiẹ̀ jẹ́ pé ipò tí ò bára dé ló wà. Mo kí i káàbọ̀, bó sì ṣe jẹ́ pé dókítà ni èmi àtàwọn arákùnrin méjì náà, ó rí ara ẹ̀ láàárín àwọn ará tó lè sún mọ́ ọn! Ìfẹ́ àti ìtìlẹ́yìn táwọn ará fi hàn sí i fún un lókun gan-an. Ó mọyì ohun táwọn ará ṣe fún un, ìyẹn ló mú kó sọ pé: “Mo mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wa yé Jèhófà, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ohun tó ṣe kọjá ohun tí mo lérò!”
Gbogbo ìgbà ni mo máa ń túbọ̀ gbára lé Jèhófà àti okun rẹ̀. Tí mo bá wà nínú mọ́tò mi tí mò ń lọ sí ibiṣẹ́ tàbí tí mò ń bọ̀ nílé, mo máa ń gbọ́ àwọn orín wa tó máa ń jáde nínú Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW, ó máa ń jẹ́ kí n lókùn, ó sì máa ń jẹ́ kára tù mí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń ràn mí lọ́wọ́, tí mo bá ti ń gbọ́ orin Jèhófà Máa Ń Dúró Tì Wá, mo máa ń kọ́ ọ tẹ̀ lé e pé: ‘Jèhófà máa ń dúró tì mí. Ó ń dì mí lọ́wọ́ mú; kí n má ṣubú; ó ń fọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ́ mi.’