Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

May 6, 2015
GUATEMALA

Àwọn Iléèwé Ní Guatemala Fẹ́ Yanjú Ìwà Jàgídíjàgan Àwọn Ọ̀dọ́; Wọ́n Béèrè Ìwé Lọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Àwọn Iléèwé Ní Guatemala Fẹ́ Yanjú Ìwà Jàgídíjàgan Àwọn Ọ̀dọ́; Wọ́n Béèrè Ìwé Lọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

ÌLÚ MẸ́SÍKÒ—Iléèwé mẹ́ta lórílẹ̀-èdè Guatemala béèrè ìwé lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n lè lò ó níléèwé wọn. Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí fi ìwé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ránṣẹ́ sí wọn ní èdè Sípáníìṣì àti Quiché. Èdè Quiché jẹ́ ọ̀kan lára èdè tí àwọn ẹ̀yà Máyà tó wà lórílẹ̀-èdè Guatemala ń sọ.

Official Rural Coeducational Elementary School ti ìlú Paraje Xepec: Olùkọ́ kan ń kọ́ àwọn ọmọ kíláàsì, ó ń lo Ìwé Ìtàn Bíbélì àti ìwé Ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ta wọ́n lọ́rẹ.

Àwọn iléèwé yìí kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé wọ́n wà lára ìwọ̀nba àwọn ètò tó ń ṣèwé jáde ní èdè Quiché, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé wọn ló sì sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro táwọn ọ̀dọ́ ní Guatemala ń kojú. Nínú ọ̀rọ̀ tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Maria Cortez láti àjọ Official Rural Coeducational Elementary School ní Paraje Xepec fi ránṣẹ́, ó sọ ìdí tí wọ́n fi béèrè àwọn ìwé náà pé ó jẹ́ láti “ṣèrànwọ́ kí ìwà rere àti ìwà ọmọlúwàbí tó ṣe pàtàkì láwùjọ má báa pòórá.”

Elisa Molina de Sthall Official Rural Coeducational School: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ka Ìwé Ìtàn Bíbélì lédè Quiché.

Ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ìwà ọ̀daràn àti ìwà jàgídíjàgan láàárín àwọn ọ̀dọ́ ti wá gbòde kan jákèjádò orílẹ̀-èdè Guatemala. Fún ìdí yìí, wọ́n ti da àwọn àjọ kan sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Guatemala bí àjọ Violence Prevention Program (VPP) láti ran àwọn “akẹ́kọ̀ọ́, òbí, olùkọ́, àwọn aláṣẹ àdúgbò àti àwùjọ lápapọ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́, kí wọ́n sì ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa mú kí ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́ dí tí wọn ò fi ní máa hùwà jàgídíjàgan.” Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn àjọ mélòó kan béèrè fún Ìwé Ìtàn Bíbélì ní èdè Quiché. Àwọn àjọ náà ni àjọ National Institute of Basic Education with Agricultural Orientation (INEBOA), àjọ Elisa Molina de Sthall Official Rural Coeducational School (EORM), àti àjọ Official Rural Coeducational Elementary School ti ìlú Paraje Xepec. Àjọ INEBOA tún béèrè fún ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ Apá Kìíní àti Apá Kejì ní èdè Sípáníìṣì. Iléèwé náà tún fún àwọn òbí ní àwọn ìwé náà kí wọ́n lè máa ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá wọn ní ìmúrasílẹ̀ fún kíláàsì tí wọ́n ti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àṣà. Kódà, ilé ìwé náà tún fi fídíò Ọmọ Onínàákúnàá Pa Dà Wálé kún ohun tí wọ́n á máa fi kẹ́kọ̀ọ́.

Erick De Paz, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Guatemala sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olórí iṣẹ́ wa ni pé ká kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé wọn, síbẹ̀ inú wa dùn pé àwọn ìwé wa tún wúlò fún àwọn olùkọ́ àtàwọn òbí láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000

Guatemala: Juan Carlos Rodas+502 5967 6015

Mexico: Gamaliel Camarillo, tẹlifóònù +52 555 133 3048