Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 6, 2019
FARANSÉ

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Orílẹ̀-èdè Faransé Ṣí Ibi Àfihàn Tuntun Kan Tí Wọ́n Kó Onírúurú Bíbélì Sí

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Orílẹ̀-èdè Faransé Ṣí Ibi Àfihàn Tuntun Kan Tí Wọ́n Kó Onírúurú Bíbélì Sí

Ní July 25, 2019, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Faransé ṣí ibi àfihàn tuntun kan tí wọ́n kó onírúurú Bíbélì sí ní ìlú Louviers, tó tó ọgọ́rùn-ún kan (100) kìlómítà sí ìlú Paris. Àkọ́lé tí a fún ibi Àfihàn Bíbélì yìí ni “Orúkọ Ọlọ́run àti Bíbélì Lédè Faransé.”

Ojúlówó Bíbélì èdè Faransé tí Olivétan ṣe lọ́dún 1545

Ibi àfihàn yìí ní àwọn Bíbélì tó ṣe pàtàkì lédè Faransé, tí kò sì tún fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Ọ̀kan lára Bíbélì tó ṣe pàtàkì jù ni ojúlówó ìtumọ̀ Bíbélì èdè Faransé tí Olivétan ṣe, tí wọ́n tẹ̀ jáde ní 1535, wọ́n tún máa ń pè é ní “La Bible de Serrières.” Bíbélì yìí ni àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítàntì kọ́kọ́ mú jáde lódindi lédè Faransé. Òhun sì ni Bíbélì àkọ́kọ́ lédè Faransé tí a tú láti inú Bíbélì tí wọn kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ó kó ipa ribiribi lórí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n tẹ̀ lẹ́yìn náà, títí kan Matthew’s Bible tí a tẹ̀ ní 1537 lédè Gẹ̀ẹ́sì, Geneva Bible lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Geneva Bible lédè Faransé. Àwọn Bíbélì ìpilẹ̀sẹ̀ míì tí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ tó wà níbi àfihàn náà ni Bíbélì Jacques Lefèvre d’Étaples tó jẹ́ àtúnṣe kẹta ti ọdún 1541 lédè Faransé, àwọn Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ Inú Bíbélì lédè Látìn ti ọdún 1541 pẹ̀lú Bíbélì Látìn ti ọdún 1545 tí Robert Estienne tó jẹ́ òntẹ̀wé ara Paris tẹ̀ jáde àti Bíbélì Faransé ti ọdún 1557 tí Jean de Tournes òntẹ̀wé ara Lyon tẹ̀ jáde.

Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ Inú Bíbélì Lédè Látìn ti ọdún 1541 (apá òsì lókè) àti Bíbélì Robert Estienne lédè Látìn ti 1545 (ààrin ní ìsàlẹ̀); Bíbélì Faransé ti 1557 látọwọ́ Jean de Tournes (apá ọ̀tún lókè). Àwọn àmì tó wà lójú ìwé yìí ń tọ́ka sí orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà bó ṣe wà nínú Bíbélì

Gbogbo àwọn Bíbélì yìí, èyí tí Olivétan ṣe, Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ Inú Bíbélì Lédè Látìn pẹ̀lú Bíbélì lédè Látìn tí Estienne ṣe àti Bíbélì Jean de Tournes, ló lo orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà. Àwọn kan ló fi àwọn Bíbélì yìí ṣètọrẹ fún ẹ̀ka tó ń bójú tó ibi àfihàn ní orílè-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Warwick, nílùú New York. Láfikún sí àwọn Bíbélì tí a ti kó jọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Faransé.

Enrique Ford tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Ṣàfihàn Àwọn Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé sọ pé: “Ibi àfihàn Bíbélì tuntun tó wà ní ọ́fíìsì wa ní Faransé sọ ìtàn tó gbádùn mọ́ni nípa Bíbélì lédè Faransé. Ó tún jẹ́ ká rí ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà wà nínú Bíbélì. A ṣì ń bá a lọ láti máa wá àwọn Bíbélì tó wúni lórí tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ tí a lè kó sí àwọn ibi àfihàn wa tó wà kárí ayé.”