MARCH 8, 2017
RỌ́ṢÍÀ
Ṣé Kì Í Ṣe Pé Wọ́n Máa Tó Fòfin De Gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà?
Ní February 21, 2017, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pàṣẹ tuntun kan. Wọ́n ní kí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún àwọn ní ìsọfúnni nípa gbogbo ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé igba àti mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [2,277] tó wà jákèjádò Rọ́ṣíà.
Ìgbà tí Agbẹjọ́rò Àgbà pàṣẹ pé kí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ lọ yẹ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà wò ni wọ́n pa àṣẹ tuntun yìí. Nígbà àyẹ̀wò yẹn, àwọn ibi táwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin nìkan làwọn aláṣẹ gbájú mọ́. Lára rẹ̀ ni Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà fúnra rẹ̀, títí kan àwọn ibòmíì tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin láwọn ìlú káàkiri orílẹ̀-èdè náà, èyí tí àwọn ìjọ ti máa ń ṣe ìjọsìn. Ní February 27, 2017, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ parí àyẹ̀wò tí wọ́n ń ṣe, wọ́n sì jábọ̀ pé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà ti rúfin, àti pé àmì wà pé wọ́n ń lọ́wọ́ sí “iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn.”
Ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rọ́ṣíà ń ká àwọn ará wọn tó wà kárí ayé lára gan-an. Àṣẹ tuntun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ gbé kalẹ̀ yìí fi hàn pé wọ́n ti dájú sọ àwọn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Pẹ̀lú ìgbésẹ̀ táwọn aláṣẹ gbé yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé kì í kàn ṣe pé Agbẹjọ́rò Àgbà fẹ́ gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ṣe ni wọ́n tún fẹ́ fòfin de gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.