Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸLIFÍṢỌ̀N JW

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—Tẹlifíṣọ̀n JW (Lórí Roku)

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—Tẹlifíṣọ̀n JW (Lórí Roku)

Ó lè jẹ́ pé ohun tó ò ń wá ò tọ̀nà. Wo ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a pè ní Bó O Ṣe Lè Fi Tẹlifíṣọ̀n JW Sórí Ẹ̀rọ. Ohun míì tún ni pé ó lè jẹ́ pé kò lè bá ẹ̀rọ tó ò ń lò ṣiṣẹ́. Tẹlifíṣọ̀n JW ò lè ṣiṣẹ́ lórí àwọn ẹ̀rọ Roku tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe jáde.

Wo àwọn èdè tó wà lórí Roku. Tó o bá fẹ́ yí èdè pa dà, lọ sí Settings níbi ìbẹ̀rẹ̀, kó o sì tẹ Yan Èdè.

 

Ọ̀fẹ́ lo lè wa ètò ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW jáde, kó o sì lò ó.

 

Tó o bá fẹ́ ṣí àkáǹtì sórí Roku, ó gba pé kó o ní káàdì ìrajà tó ń ṣiṣẹ́ torí kì í ṣe gbogbo ohun tó wà ní Roku Channel Store ló jẹ́ ọ̀fẹ́. Àmọ́ tó o bá fẹ́ ran nǹkan nìkan ni wọ́n máa yọwó ẹ. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, lọ sórí abala ìrànlọ́wọ́ Roku.

 

Bọ́tìnì Fi Àkọlé Hàn ò sí lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí fún àwọn fídíò Tẹlifíṣọ̀n JW kan tá a gbé jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí tó wà lórí Roku, á tó oṣù mélòó kan kó o tó lè rí i. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, àwọn tó ń lo Roku tí wọ́n sì fẹ́ rí àwọn àkọlé yìí lè lọ wò ó lórí kọ̀ǹpútà tàbí lórí fóònù tó lè lọ sórí ìkànnì tv.jw.org. Lórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà yẹn, tó o bá fẹ́ kó gbé àkọlé wá, tẹ Wo àwọn àkọlé tó bá wà níbi Settings.

 

Ọ̀rẹ́ rẹ tó mọ̀ nípa Roku tàbí Tẹlifíṣọ̀n JW lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tí ìbéèrè ẹ bá jẹ mọ́ ẹ̀rọ Roku tó ò ń lò tàbí àkáǹtì tó o ní lórí ìkànnì, lọ sí abala ìrànlọ́wọ́ lórí ìkànnì Roku. Tó o bá níṣòro pẹ̀lú ètò ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW, jọ̀ọ́, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó sún mọ́ ẹ jù.