Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸLIFÍṢỌ̀N JW

Bó O Ṣe Lè Wá Àtẹ́tísí àti Fídíò Lórí TV.JW.ORG

Bó O Ṣe Lè Wá Àtẹ́tísí àti Fídíò Lórí Amazon Fire TV

O lè wá nǹkan lórí Tẹlifíṣọ̀n JW ní apá tá a pè ní Wá a.

Níbi ìbẹ̀rẹ̀, lọ sí apá tá a pè ní Search kó o wá tẹ Select kó lè gbé àpótí tá a fi ń wá nǹkan wá. Tún tẹ Select kó o lè bẹ̀rẹ̀ sí í wá ohun tó o fẹ́ wá.

Nínú àpótí náà, tẹ ọ̀rọ̀ tó o lè fi dá ohun tó ò ń wá mọ̀, kó o wá tẹ Select. Bí àpẹẹrẹ, o lè tẹ díẹ̀ lára àkòrí ẹ̀ síbẹ̀ tàbí kó o tẹ orúkọ ẹni tó dá lé tàbí ohun tí wọ́n ṣe nínú fídíò tàbí àtẹ́tísí náà. Bó o bá ṣe ń tẹ ọ̀rọ̀ láá ti máa gbé àwọn èyí tó jọ ọ́ wá. Lo bọ́tìnì Up, Down, Left àti Right tó wà lórí rìmóòtù ẹ láti lọ sórí àwòrán tàbí àkòrí fídíò tàbí àtẹ́tísí tó o fẹ́, kó o wá tẹ Select.

Tó o bá fẹ́ wá ọ̀rọ̀ kan pàtó nínú àkòrí fídíò tàbí àtẹ́tísí náà, tẹ ọ̀rọ̀ náà, kó o fi àmì bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, kó o sì fi àmì parí rẹ̀.

Oríṣiríṣi àtẹ́tísí àti fídíò ló máa gbé wá fún ẹ. Tó o bá fẹ́ kí ohun tó ń gbé wá túbọ̀ ṣe ṣàkó, tẹ bọ́tìnì Fídíò kó lè gbé fídíò nìkan wa, tàbí kó o tẹ bọ́tìnì Àtẹ́tísí kó lè gbé àtẹ́tísí nìkan wá.

Fídíò tàbí àtẹ́tísí mẹ́rìnlélógún (24) àkọ́kọ́ tó bá ọ̀rọ̀ tó o tẹ̀ mu jù ló máa kọ́kọ́ gbé wá. Wàá rí àpapọ̀ iye fídíò tàbí àtẹ́tísí tó rí (bí àpẹẹrẹ, “Ò ń wo 24 nínú 28”).

Tó ò bá rí ohun tó ò ń wá, tẹ ọ̀rọ̀ tó túbọ̀ ṣe ṣàkó. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ ètò oṣooṣù kan pàtó lò ń wá, àmọ́ tó o tẹ “eto osoosu”, á dáa kó o fi oṣù àti ọdún tó jẹ́ sí i, orúkọ arákùnrin tó ṣe atọ́kùn tàbí ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yẹn.