Privacy Settings

To provide you with the best possible experience, we use cookies and similar technologies. Some cookies are necessary to make our website work and cannot be refused. You can accept or decline the use of additional cookies, which we use only to improve your experience. None of this data will ever be sold or used for marketing. To learn more, read the Global Policy on Use of Cookies and Similar Technologies. You can customize your settings at any time by going to Privacy Settings.

JW LIBRARY

Pinnu Bó O Ṣe Fẹ́ Kí Ìwé Tó Ò Ń Kà Rí​—Lórí Android

Pinnu Bó O Ṣe Fẹ́ Kí Ìwé Tó Ò Ń Kà Rí​—Lórí Android

Àwọn ohun mélòó kàn wà nínú JW Library tó máa jẹ́ kó o lè pinnu bó o ṣe fẹ́ kí ìwé tó ò ń kà rí. Wàá rí wọn lápá òkè lójú fóònù ẹ tó o bá ń ka orí ìwé kan tàbí àpilẹ̀kọ kan.

Tó-tò-tó

Ó lè gba pé kó o tẹ àmì tó-tò-tó kó o lè rí díẹ̀ lára wọn.

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè pinnu bó o ṣe fẹ́ kí ìwé tó ò ń kà rí:

 Yí Èdè Pa Dà

O lè yí èdè orí ìwé tàbí àpilẹ̀kọ tó ò ń kà lọ́wọ́ pa dà.

  • Èdè

    Tẹ àmì Èdè kó o lè rí gbogbo èdè tí ojú ìwé tó ò ń kà wà. Àwọn èdè tó ò ń lò jù ló máa wà lókè pátápátá. Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó rọrùn náà máa hàn níbí. O tún lè wá èdè kan tó o bá fi orúkọ èdè náà wá a.

  • Òfúrufú

    Wàá rí àmì òfúrufú lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìwé èdè kan tó ò tíì wà jáde. Tẹ ìwé kan kó o lè wà á jáde. Tí ìwé náà bá ti dórí fóònù ẹ, o ò ní rí àmì òfúrufú yẹn níbẹ̀ mọ́. Tún tẹ ìwé náà kó o lè kà á.

 Mú Kí Ọ̀rọ̀ Tóbi Tàbí Kó Kéré

O lè mú kí ọ̀rọ̀ tóbi tàbí kó kéré bó bá ṣe rò ẹ́ lọ́rùn kó o lè rí i kà.

Mú Kí Ọ̀rọ̀ Tóbi Tàbí Kéré

Tẹ bọ́tìnì Text Settings, kó o wá fa ìlà tó o rí kó o lè mú kí ọ̀rọ̀ tóbi tàbí kó kéré. Bí ọ̀rọ̀ bá ṣe tóbi tó níbẹ̀ ló ṣe máa rí nínú gbogbo ìwé tó wà lórí JW Library.

 Ṣe É ní Àwòrán Tàbí Ọ̀rọ̀

Àwọn àpilẹ̀kọ kan wà tó o lè ṣe kó rí bí àwòrán tàbí ọ̀rọ̀. Tẹ èyí tó o bá fẹ́, kó o sì yí i pa dà nígbàkigbà tó o bá fẹ́.

  • Ṣe É ní Àwòrán

    View Image: Èyí máa jẹ́ kí àpilẹ̀kọ náà rí bó ṣe máa rí lọ́rí ìwé gangan. Bí àwọn kan ṣe máa ń fẹ́ kó rí nìyẹn tí wọ́n bá ń lo àwọn ìwé bí ìwé orin. Tí wọ́n bá ṣe é lọ́nà yìí, wọ́n máa rí àwọn àmì orin.

  • Ṣe É ní Ọ̀rọ̀

    View Text: Èyí máa jẹ́ kí àwọn ẹsẹ Bíbélì ní ìlujá tó ṣeé tẹ̀, ọ̀rọ̀ sì máa tóbi tàbí kéré bó o bá ṣe fẹ́ kó rí.

 Ṣí I ní . . .

Apá tá a pè ní Open in . . . máa jẹ́ kó o lè wo àwọn ohun tó wà lórí JW Library níbòmíì.

Ṣí I ní
Àká Ìwé Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì

Tẹ Open in . . . kó o lè rí àwọn ibi tó o ti lè wò ó. Bí àpẹẹrẹ, o lè tẹ Open in Online Library kó o lè ṣí ibi tó ò ń kà lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí Watchtower ONLINE LIBRARY.

 To Bíbélì Lọ́nà Tó O Fẹ́

Tó o bá tẹ ẹsẹ Bíbélì kan nínú ìtẹ̀jáde kan, ó máa gbé e wá. Tẹ bọ́tìnì Customize tó wà nísàlẹ̀ pátápátá ẹsẹ Bíbélì yẹn kó o lè yan àwọn Bíbélì tó o ti wà jáde tẹ́lẹ̀ tó o máa fẹ́ kó hàn nígbàkigbà tó o bá tẹ ẹsẹ Bíbélì kan.

Fi Kún Un Tàbí Yọ Ọ́ Kúrò

Tẹ Add tàbí Remove kó o lè yọ àwọn Bíbélì kan kúrò tàbí kó o fi kún un. O lè fa àwọn Bíbélì náà sókè tàbí sísàlẹ̀ kó o lè tún wọn tò bó o ṣe fẹ́.

Wo “Bó O Ṣe Lè Wa Bíbélì Jáde Kó O sì Máa Lò Ó​—Lórí Android” kó o lè mọ bó o ṣe lè wa àwọn Bíbélì míì jáde lórí JW Library.

February 2015 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.4 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí Android 2.3 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Lórí Android,” lábẹ́ Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.