ÌKÀNNÌ JW.ORG
Bó O Ṣe Lè Wá Ìtẹ̀jáde
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé, àtẹ́tísí àti fídíò ló wà ní apá tá a pè ní ÌTẸ̀JÁDE lórí ìkànnì jw.org. Tẹ̀ lé àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí kó o lè rí ìtẹ̀jáde tó ò ń wá.
Fi Àkòrí Kan Pàtó Wá Ìtẹ̀jáde
Tó o bá ti mọ àkòrí ìtẹ̀jáde kan tàbí tó o mọ díẹ̀ lára àkòrí náà, lo ọ̀nà tá a ṣàlàyé sísàlẹ̀ yìí láti tètè wá ìtẹ̀jáde náà.
Lọ sí ÌTẸ̀JÁDE > ÌWÉ ŃLÁ ÀTI ÌWÉ PẸLẸBẸ.
Tẹ àpótí Gbogbo Rẹ̀, kó o sì tẹ ọ̀rọ̀ kan látinú àkòrí ìtẹ̀jáde tó ò ń wá. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lò ń wá, tẹ “koni.” Àwọn ìtẹ̀jáde tí “koni” wà nínú àkòrí ẹ̀ nìkan ló máa gbé wá. O lè wá yan ìwé tó ò ń wá.
Tẹ bọ́tìnì Wá a.
Wá Ìwé Ìròyìn Kan Pàtó
Lọ sí ÌTẸ̀JÁDE > ÌWÉ ÌRÒYÌN.
Tó bá ti kọ́kọ́ gbé abala ìwé ìròyìn wá, ìwé ìròyìn Jí! àti Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà tá à ń fi sóde) mẹ́rin tó dé kẹ́yìn àti ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́) lo máa rí. Tó bá ní ọ̀kan pàtó tó ò ń wá, tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí:
Níbi àwọn àpótí tó o rí lókè, yan irú ìwé ìròyìn tó ò ń wá àti ọdún tó jáde.
Tẹ bọ́tìnì Wá a.
Wo Gbogbo Oríṣi Ẹ̀dà Ìtẹ̀jáde Kan Tó O Lè Wà Jáde
Oríṣi ọ̀nà méjì lo lè gbà to ìtẹ̀jáde—tò ó pẹ̀lú àwòrán tàbí kó o tò ó gbọọrọ.
Tẹ bọ́tìnì Tò Ó Pẹ̀lú Àwòrán kó o lè rí àwọn ìtẹ̀jáde tó wà. Báyìí ni kọ̀ǹpútà ṣe máa ń to ìtẹ̀jáde, àfi tó o bá yí i pa dà.
Bọ́tìnì Tò Ó Pẹ̀lú Àwòrán máa jẹ́ kó o rí èèpo ẹ̀yìn ìwé, àmì tó o máa tẹ̀ láti wà á jáde àti àkòrí ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan. Sún mouse ẹ lórí àmì tó o máa tẹ̀ láti wà á jáde (tàbí kó o tẹ àmì náà tó bá jẹ́ fóònù lò ń lò) kó o lè rí gbogbo oríṣi ẹ̀dà ìtẹ̀jáde náà tó o lè wà jáde (bóyá ti orí ìwé ni àbí àtẹ́tísí).
Tẹ bọ́tìnì Tò Ó Gbọọrọ kó o lè yí ọ̀nà tó gbà tò ó pa dà.
Bọ́tìnì Tò Ó Gbọọrọ máa jẹ́ kó o rí gbogbo oríṣi ẹ̀dà ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan tó o lè wà jáde.
Àwọn ìwé kan ní ẹ̀dà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, bí ìwé oní lẹ́tà gàdàgbà. Yan irú ẹ̀dà kan (bí àpẹẹrẹ, PDF) kó o lè rí gbogbo oríṣi ẹ̀dà ẹ̀ tó wà. Tẹ ìlujá ẹ̀dà tó o fẹ́ wà jáde.
Wá Ìtẹ̀jáde Tó Ní Ohun Kan Pàtó
Tó bá jẹ́ pé ìwé kan wà tó ṣeé kà lórí ìkànnì, lo apá tá a pè ní Wá a láti wá àpilẹ̀kọ tàbí orí ìwé náà tó ní ọ̀rọ̀ kan pàtó tó ò ń wá.
Tẹ bọ́tìnì Wá a. Nínú àpótí tó o máa tẹ ọ̀rọ̀ sí, tẹ ọ̀rọ̀ tó ò ń wá, kó o wá tẹ bọ́tìnì Wá a. Tó o bá mọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé náà, tẹ̀ ẹ́ sí i. Èyí lè mú kí kọ̀ǹpútà tètè fi àpilẹ̀kọ tàbí orí ìwé tó ò ń wá náà sára èsì tó o máa kọ́kọ́ rí.
Tó o bá fẹ́ dín iye àpilẹ̀kọ tó o máa rí nínú èsì tí kọ̀ǹpútà gbé wá kù, tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí:
Tẹ Wá A Dáadáa tàbí ìlujá Ṣe Ètò Sí I.
Lábẹ́ ìsọ̀rí Ibi Tó O Ti Fẹ́ Wá A, sàmì sí àpótí Ìtẹ̀jáde.
Tẹ bọ́tìnì Wá a.