Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

A Fẹ́ Kó O Wá

Ìrántí Ikú Jésù

Saturday, April 12, 2025

A fẹ́ kó o wá sí àwọn ìpàdé méjì yìí, a ò sì ní gba owó níbẹ̀

Àkànṣe Àsọyé Tó Dá Lórí Bíbélì

“Ibo La Ti Lè Rí Òtítọ́?”

Wàá rí ohun tí Jésù sọ nípa òtítọ́ àti bá a ṣe lè rí i.

Wá Ibi Tó O Ti Máa Gbọ́ Àkànṣe Àsọyé

Ìrántí Ikú Jésù

Níbi ìpàdé yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń rántí ikú Jésù bó ṣe pa á láṣẹ.—Lúùkù 22:19.

Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè

Àwọn wo ló lè wá?

Gbogbo èèyàn la pè, kódà ìwọ àti ìdílé ẹ lè jọ wá.

Báwo làwọn ìpàdé yìí ṣe máa pẹ́ tó?

Ọgbọ̀n (30) ìṣẹ́jú ni àkànṣe àsọyé náà máa jẹ́. Lẹ́yìn náà, a máa fi wákàtí kan jíròrò àkòrí Bíbélì kan, gbogbo àwùjọ sì máa láǹfààní láti sọ̀rọ̀.

Nǹkan bíi wákàtí kan la máa fi ṣe Ìrántí Ikú Jésù.

Ibo lẹ ti máa ṣe é?

Tó o bá fẹ́ mọ ibi tá a ti máa ṣe é ládùúgbò ẹ, tẹ ìlujá “Wá Ibi Tá A Ti Máa Ṣe Ìrántí Ikú Kristi” tàbí “Wá Ibi Tó O Ti Máa Gbọ́ Àkànṣe Àsọyé.”

Ṣé màá san owó ìwọlé àbí mo gbọ́dọ̀ gbà láti wá sáwọn ìpàdé mí ì?

Rárá.

Ṣé ẹ máa gbé igbá ọrẹ?

Rárá. A kì í gbégbá ọrẹ láwọn ìpàdé wa.​​—⁠Mátíù 10:⁠8.

Ṣé ó nírú aṣọ tí mo gbọ́dọ̀ wọ̀?

Rárá. Síbẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá láti múra lọ́nà tó bójú mu.

Báwo lẹ ṣe máa ń ṣe Ìrántí Ikú Jésù?

Orin la fi máa ń bẹ̀rẹ̀ ètò náà tá a sì máa fi parí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀kan lára òjíṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa gbàdúrà. A tún máa gbọ́ àsọyé kan tó máa ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì kí Jésù kú àti bá a ṣe lè jàǹfààní látinú ohun tí Ọlọ́run àti Kristi ṣe fún wa.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Nìdí Tí Ọ̀nà Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Ń Ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Fi Yàtọ̀ sí Ti Àwọn Ẹlẹ́sìn Tó Kù?

Ìgbà wo lẹ máa ṣe Ìrántí Ikú Jésù lọ́jọ́ iwájú?

2025: Saturday, April 12

2026: Thursday, April 2

2027: Monday, March 22

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, jọ̀wọ́ wo àwọn fídíò yìí.

Ìrántí Ikú Jésù

Wàá rí bá a ṣe máa ń ṣe Ìrántí Ikú Jésù, wàá sì rí àwọn ohun àgbàyanu tí ikú Jésù máa mú kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Kí Nìdí Tí Jésù Fi kú?

Ó ṣeé ṣe kó o gbọ́ táwọn èèyàn máa ń sọ pé Jésù kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Àmọ́ ṣé ikú ẹnì kan lè ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láǹfààní?

Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?

Tó o bá lọ, ìwọ fúnra ẹ máa rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.

Wa ẹ̀dà ìwé yìí jáde.