Ojú Wo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wo Ìkọ̀sílẹ̀?
Ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀ la máa ń tẹ̀ lé. Ọlọ́run fẹ́ kí ọkùnrin àti obìnrin tó bá jọ ṣègbéyàwó bára wọn kalẹ́. Ohun kan ṣoṣo tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ó lè mú kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ ni tí ẹnì kan nínú wọn bá ṣe ìṣekúṣe.—Mátíù 19:5, 6, 9.
Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ran àwọn tọkọtaya tí wọ́n níṣòro nínú ìgbéyàwó wọn lọ́wọ́?
Bẹ́ẹ̀ ni, a máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà:
Àwọn ìtẹ̀jáde. Àwọn àpilẹ̀kọ tó lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ máa ń jáde déédéé nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, kódà, ó máa ń ran àwọn tọkọtaya tó dà bíi pé ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó wọn ti kọjá àtúnṣe lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn àpilẹ̀kọ yìí, “Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Máa Ṣera Wọn Lọ́kan,” “Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Dárí Ji Ara Yín,” àti “Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Pa Dà Máa Fọkàn Tán Ara Yín.”
Àwọn ìpàdé. Láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àtàwọn àpéjọ àgbègbè tá a máa ń ṣe, a máa ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó.
Àwọn alàgbà. Àwọn alàgbà inú ìjọ máa ń bá àwọn tọkọtaya sọ̀rọ̀, wọ́n máa ń fi ohun tó wà nínú Bíbélì ràn wọ́n lọ́wọ́, irú bí ohun tó wà nínú Éfésù 5:22-25.
Ṣé ó di dandan káwọn alàgbà ìjọ fọwọ́ sí i tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan bá fẹ́ kọ ìyàwó tàbí ọkọ rẹ̀ sílẹ̀?
Rárá. Kódà, tí àwọn alàgbà bá fẹ́ ran tọkọtaya kan tí ìgbéyàwó wọn níṣòro lọ́wọ́, wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ ohun tí tọkọtaya náà máa ṣe fún wọn. (Gálátíà 6:5) Àmọ́, tẹ́nì kan bá lóun fẹ́ kọ ìyàwó tàbí ọkọ òun sílẹ̀, láìjẹ́ pé ìyàwó tàbí ọkọ rẹ̀ ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ó lè mú kí wọ́n kọra wọn sílẹ̀, ẹni náà ò ní lè fẹ́ ẹlòmíì torí Ìwé Mímọ́ ò fọwọ́ sí ohun tó fẹ́ ṣe.—1 Tímótì 3:1, 5, 12.
Ojú wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo ìpínyà?
Bíbélì gba àwọn tọkọtaya níyànjú pé kí wọ́n má fira wọn sílẹ̀, bí nǹkan ò bá rí bó ṣe yẹ kó rí pàápàá. (1 Kọ́ríńtì 7:10-16) Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló lè yanjú tí wọ́n bá ń gbàdúrà léraléra, tí wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, tí wọ́n sì ń fìfẹ́ hàn síra wọn.—1 Kọ́ríńtì 13:4-8; Gálátíà 5:22.
Àmọ́ nígbà míì, tọ́rọ̀ náà bá le gan-an, àwọn Kristẹni máa ń pinnu pé àwọn máa pínyà. Bí àpẹẹrẹ:
Tí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti pèsè fún ìdílé rẹ̀.—1 Tímótì 5:8.
Tí ẹnì kan bá ń lu ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ ní ìlubàrà.—Sáàmù 11:5.
Tí ẹnì kan ò bá jẹ́ kí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ sin Ọlọ́run. Ká sọ pé, ẹnì kan fẹ́ fipá mú kí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ohun tó ta ko òfin Ọlọ́run lọ́nà kan, ọkọ tàbí ìyàwó tí ẹnì kejì rẹ̀ ń fipá mú yìí lè pinnu pé àfi káwọn pínyà tóun bá fẹ́ máa “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.