ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?—Apá Kìíní: Wo Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì
“Mo tí gbìyànjú láti ka Bíbélì, àmọ́ ẹ̀rù máa ń bà mí torí pé ó ti pọ̀ jù!”—Briana, 15.
Ṣé bó ṣe máa ń ṣe ìwọ náà nìyẹn? Àpilẹ̀kọ yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́!
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ka Bíbélì?
Ṣé Bíbélì máa ń sú ẹ láti kà? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń ṣe rí bẹ́ẹ̀ fún. Òótọ́ ni pé Bíbélì jẹ́ ìwé tí kò ní àwòrán, tí ojú ìwé rẹ̀ lé lẹ́gbẹ̀rún, tí wọ́n tún fi lẹ́tà wínníwínní kọ ọ́. Kò dà bíi tẹlifíṣọ̀n àtàwọn fídíò!
Wòó báyìí ná: Tó bá ṣẹlẹ̀ pé o rí àpótí ìṣura ńlá kan, ó dájú pé ó máa wù ẹ́ láti mọ nǹkan tó wà nínú ẹ̀.
Bíbélì ò yàtọ̀ sí àpótí ìṣura. Àwọn ìṣura ọgbọ́n tó wúlò gan-an ló wà nínú rẹ̀, ó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti
Ṣe ìpinnu tó tọ́
Jẹ́ kí ìwọ àtàwọn òbí rẹ mọwọ́ ara yín
Ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi
Borí ìṣòro
Àmọ́, báwo ló ṣe jẹ́ pé ìwé ayé àtijọ́ yẹn ṣì wúlò fún wa gan-an lóde òní? Ìdí ni pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì wá látọ̀dọ̀ Ẹni tó gbọ́n jù lọ láyé àti lọ́run.
Báwo ni mo ṣe lè ka Bíbélì?
Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o kà á láti páálí dé páálí. Ìyẹn máa jẹ́ kó o mọ ohun tí Bíbélì dá lé gan-an. Oríṣiríṣi ọ̀nà lo lè gbà ka Bíbélì. Wo àpẹẹrẹ méjì:
O lè bẹ̀rẹ̀ láti Jẹ́nẹ́sísì kó o sì kà á dé Ìṣípayá gẹ́lẹ́ báwọn ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] yẹn ṣe tò tẹ̀lé ara wọn.
O tún lè ka Bíbélì bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú rẹ̀ ṣe tò tẹ̀lé ara wọn, àti bí wọ́n ṣe so kọ́ra.
Ohun kan rèé: Ìwé Àfikún Ìsọfúnni Láti Lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ojú ìwé kẹrin máa ràn ẹ́ lọwọ́ kó o lè rí bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nígbà ayé Jésù ṣe tò tẹ̀léra.
Ọ̀nà kejì tó o lè gbà ka Bíbélì ni pé kó o yan ìtàn ẹnì kan nínú Bíbélì tó kojú irú ìṣòro tóò ń kojú. Bí àpẹẹrẹ:
Ṣé ò ń wá àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa, tó ṣeé fọkàn tán? Ka ìtàn Jónátánì àti Dáfídì. (1 Sámúẹ́lì, orí 18-20) Lẹ́yin náà lo ìwé àjákọ “Bí O Ṣe Lè Rí Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin,” wàá rí ẹ̀kọ́ kọ́ gan-an níbẹ̀.
Ṣé wàá fẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti borí ìdẹwò? Ka ìtàn nípa bí Jósẹ́fù ṣe borí ìdẹwò. (Jẹ́nẹ́sísì, orí 39) Lẹ́yìn náà, o lè lo ìwé àjákọ “Bí O Ṣe Lè Dènà Ìdẹwò . . . Jósẹ́fù—Apá kìíní” àti “Wọ́n Fi Ẹ̀sùn Èké Kàn Án! Jósẹ́fù—Apá kejì.” Ìtàn yìí máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ gan-an.
Ṣé wàá fẹ́ mọ bí àdúrà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ka ìtàn Nehemáyà. (Nehemáyà, orí 2) Lẹ́yìn náà, lo ìwé àjákọ náà “Ọlọ́run Dáhùn Àdúrà Rẹ̀.” Ìtàn yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Ohun kan rèé: Rí i dájú pé kò sí ariwo nígbà tó o bá fẹ́ ka Bíbélì, ìyẹn máa jẹ́ kó o pọkàn pọ̀.
Ọ̀nà kẹta tó o lè gbà ka Bíbélì ni pé kó o yan ìtàn kan tàbí ibì kan nínú Sáàmù, kó o sì kà á. Lẹ́yìn náà, wo àwọn ẹ̀kọ́ tó o lè rí kọ́ látinú ìtàn yẹn. Tó o bá ti kà á tán, bi ara rẹ pé:
Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí apá yìí wà nínú Bíbélì?
Kí ló kọ́ mi nípa Jèhófà, àti bó ṣe ń ṣe nǹkan?
Báwo ni mo ṣe lè fi àwọn kókó yìí sílò láyé mi?
Ohun tó o lè ṣe: Ní àfojúsùn! Kọ déètì ọjọ́ tó o máa wù ẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ Bíbélì kíkà sílẹ̀.