Ta Ni Máíkẹ́lì, Olú-Áńgẹ́lì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ó ṣe kedere pé Máíkẹ́lì, táwọn ẹlẹ́sìn kan máa ń pè ní “Máíkẹ́lì Mímọ́,” ni orúkọ tí Jésù ń jẹ́ kó tó wá sáyé àti lẹ́yìn tó pa dà sọ́run. a Máíkẹ́lì bá Sátánì fa ọ̀rọ̀ lẹ́yìn ikú Mósè, ó sì ran áńgẹ́lì kan lọ́wọ́ kó lè ráyè dé ọ̀dọ̀ wòlíì Dáníẹ́lì lọ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an. (Dáníẹ́lì 10:13, 21; Júúdà 9) Ìtumọ̀ orúkọ Máíkẹ́lì ni “Ta Ló Dà Bí Ọlọ́run?”, orúkọ yìí sì ń rò ó torí ó ń gbèjà Ọlọ́run pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, ó sì ń bá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run jà.—Dáníẹ́lì 12:1; Ìṣípayá 12:7.
Wo ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu ká gbà pé Jésù ni Máíkẹ́lì, olú-áńgẹ́lì.
Máíkẹ́lì ni “olú-áńgẹ́lì.” (Júúdà 9) Ìtumọ̀ “olú-áńgẹ́lì” ni “olórí àwọn áńgẹ́lì,” inú ẹsẹ Bíbélì méjì péré ni ọ̀rọ̀ náà sì wà. Bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ yìí nínú àwọn ẹsẹ méjì yìí fi hàn pé áńgẹ́lì kan péré ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé Jésù Olúwa tó ti jíǹde máa “sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú-áńgẹ́lì.” (1 Tẹsalóníkà 4:16) Jésù ní “ohùn olú-áńgẹ́lì” torí pé òun ni Máíkẹ́lì, olú-áńgẹ́lì.
Máíkẹ́lì ní àwọn ọmọ ogun tí wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì. “Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun,” ìyẹn Sátánì. (Ìṣípayá 12:7) Máíkẹ́lì láṣẹ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀dá ẹ̀mí, kódà Bíbélì pè é ní “ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ó wà ní ipò iwájú pátápátá” àti “ọmọ aládé ńlá.” (Dáníẹ́lì 10:13, 21; 12:1) Ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ mú kí ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ David E. Aune, tó ń ṣèwádìí lórí Májẹ̀mú Tuntun pe Máíkẹ́lì ní “ọ̀gágun àwọn áńgẹ́lì.”
Orúkọ ẹnì kan péré ni Bíbélì tún dá pé ó ní àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ áńgẹ́lì. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó tí ń mú ẹ̀san wá.” (2 Tẹsalóníkà 1:7, 8; Mátíù 16:27) Nígbà tí Jésù dé “ọ̀run, a . . . fi àwọn áńgẹ́lì àti àwọn aláṣẹ àti àwọn agbára sábẹ́ rẹ̀.” (1 Pétérù 3:21, 22) Ó máa rí bákan, kí Ọlọ́run fi Jésù àti Máíkẹ́lì ṣe olórí àwọn áńgẹ́lì. Ó ṣe tán, ọba méjì kì í ṣáà jẹ nílùú kan. Àmọ́ ó bọ́gbọ́n mu ká gbà pé ẹnì kan náà ló ń jẹ́ orúkọ méjèèjì, ìyẹn Jésù àti Máíkẹ́lì.
Máíkẹ́lì máa “dìde dúró” ní “àkókò wàhálà” tírú ẹ̀ ò wáyé rí. (Dáníẹ́lì 12:1) Nínú ìwé Dáníẹ́lì, ọ̀rọ̀ náà “dìde dúró” sábà máa ń tọ́ka sí ọba kan tó fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì kan. (Dáníẹ́lì 11:2-4, 21) Jésù Kristi, tí Bíbélì pè ní “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run torí òun ni “Ọba àwọn ọba,” á sì gbèjà àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ìṣípayá 19:11-16) Ìgbà “ìpọ́njú ńlá . . ., irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé” ló máa ṣe é—Mátíù 24:21, 42.
a Bíbélì pe àwọn èèyàn kan láwọn orúkọ míì, bí àpẹẹrẹ, Jákọ́bù (tó tún ń jẹ́ Ísírẹ́lì), Pétérù (tó tún ń jẹ́ Símónì) àti Tádéọ́sì (tó tún ń jẹ́ Júdásì).—Jẹ́nẹ́sísì 49:1, 2; Mátíù 10:2, 3; Máàkù 3:18; Ìṣe 1:13.