Ǹjẹ́ Ọlọ́run Á Gbọ́ Mi Tí Mo Bá Gbàdúrà?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run máa ń ran àwọn tó bá fi tinútinú tọrọ ohun tó bá bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Kódà tó ò bá tíì gbàdúrà rí, ó máa wú ẹ lórí tó o bá wo àpẹẹrẹ àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n gbàdúrà pé “Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́.” Wò ó bí àpẹẹrẹ:
“Ran mi lọwọ, Oluwa Ọlọrun mi: gbà mi gẹgẹ bi ãnu rẹ.”—Orin Dafidi 109:26, Bibeli Mimọ.
“Aláìnì àti tálákà ni mí: Ọlọ́run jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́.”—Sáàmù 69:6, Douay Version.
Òótọ́ ni pé àwọn tó nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run làwọn tó kọ ọ̀rọ̀ yìí. Síbẹ̀, Ọlọ́run máa ń gbọ́ ti gbogbo ẹni tó bá tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú ẹ̀mí tó dára, irú bí àwọn “oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà” tàbí àwọn “tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀.”—Sáàmù 34:18.
Má ṣe rò pé Ọlọ́run jìnnà sí ọ kọjá kó fẹ́ mọ ohun tó ń dà ọ́ láàmú. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀; Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.” (Sáàmù 138:6) Kódà Jésù tiẹ̀ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà.” (Mátíù 10:30) Ọlọ́run mọ̀ ọ́ kọjá ibi tó o mọ ara rẹ dé. Torí náà, ó máa tẹ́tí sí ọ tó bá gbàdúrà sí i pé kó bá ọ bójú tó àwọn ohun tó ò ń ṣàníyàn lé lórí!—1 Pétérù 5:7.