Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

“Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù”​—Ṣé Èèyàn Máa Rí Ìgbàlà Tó Bá Ṣáà Ti Gba Jésù Gbọ́?

“Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù”​—Ṣé Èèyàn Máa Rí Ìgbàlà Tó Bá Ṣáà Ti Gba Jésù Gbọ́?

Ohun tí Bíbélì sọ

Àwa Kristẹni gbà gbọ́ pé Jésù kú torí ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé. (1 Pétérù 3:18) Àmọ́, ká tó lè rí ìgbàlà, ó ju ká kàn gbà pé Jésù ni Olùgbàlà. Ó ṣe tán, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá mọ̀ pé “Ọmọ Ọlọ́run” ni Jésù, síbẹ̀ Ọlọ́run máa pa wọ́n run, wọn ò ní rí ìgbàlà.​—Lúùkù 4:41; Júùdù 6.

 Kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n tó lè rí ìgbàlà?

  • O gbọ́dọ̀ gbà pé Jésù fẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Ìṣe 16:30, 31; 1 Jòhánù 2:2) O tún gbọ́dọ̀ gbà pé Jésù jẹ́ ẹni gidi kan àti pé gbogbo ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ ló jóòótọ́.

  • Kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an. (2 Tímótì 3:15) Bíbélì sọ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Sílà sọ fún ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan pé: “Gba Jésù Olúwa gbọ́, wàá sì rí ìgbàlà.” Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ ní “ọ̀rọ̀ Jèhófà.” a (Ìṣe 16:31, 32) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn fi hàn pé kí ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn tó lè gba Jésù gbọ́ ní ti gidi, ó gbọ́dọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dé ìwọ̀n àyè kan. Ó gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ pípéye nínú Ìwé Mímọ́.​—1 Tímótì 2:3, 4.

  • Ronú pìwà dà. (Ìṣe 3:19) Ó tún yẹ kó o ronú pìwà dà tàbí lédè míì, kó o kábàámọ̀ àwọn ohun tí kò dáa tó o ti ṣe sẹ́yìn. Àwọn èèyàn máa mọ̀ pé o ti ronú pìwà dà tó o bá jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí Ọlọ́run kórìíra, tó o sì ń ṣe “àwọn iṣẹ́ tó fi ìrònúpìwàdà hàn.”​—Ìṣe 26:20.

  • Ṣe ìrìbọmi. (Mátíù 28:19) Jésù sọ pé ẹni tó bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn òun gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi. Ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣèrìbọmi. (Ìṣe 16:33) Bákan náà, lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ní òtítọ́ nípa Jésù, “àwọn tó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ìrìbọmi.”​—Ìṣe 2:40, 41.

  • Máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jésù. (Hébérù 5:9) Àwọn tó bá ń “pa gbogbo ohun” tí Jésù pa láṣẹ mọ́ máa ń fi hàn nínú ìgbésí ayé wọn pé ọmọlẹ́yìn Jésù làwọn. (Mátíù 28:20) Wọ́n máa ń ‘ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ, kì í ṣe pé kí wọ́n máa gbọ́ ọ lásán.’​—Jémíìsì 1:22.

  • Fara dà á dópin. (Máàkù 13:13) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù “nílò ìfaradà” kí wọ́n tó lè rí ìgbàlà. (Hébérù 10:36) Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run látìgbà tó ti di Kristẹni títí tó fi kú.​—1 Kọ́ríńtì 9:27.

 Kí ni wọ́n ń pè ní Àdúrà Ẹlẹ́ṣẹ̀?

Nínú àwọn ẹ̀sìn kan, wọ́n máa ń gba àdúrà kan tí wọ́n ń pè ní Àdúrà Ẹlẹ́ṣẹ̀ àti Àdúrà Ìgbàlà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó máa ń gbàdúrà yìí gbà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ làwọn àti pé Jésù kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọ́n tún máa ń gbàdúrà pé kí Jésù wọnú ọkàn wọn tàbí kó jọba láyé wọn. Àmọ́, Bíbélì kò sọ̀rọ̀ nípa “Àdúrà Ẹlẹ́ṣẹ̀,” kò sí ní ká máa gba irú àdúrà bẹ́ẹ̀.

Àwọn kan rò pé tẹ́nì kan bá ti gba “Àdúrà Ẹlẹ́ṣẹ̀,” ó dájú pé ẹni náà máa rí ìgbàlà àti ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́, torí pé à ń gbàdúrà ò túmọ̀ sí pé a máa rígbàlà. Ó ṣe tán, aláìpé ni wá, kò sì sígbà tá ò ní máa ṣàṣìṣe. (1 Jòhánù 1:8) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi ní kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa gbàdúrà léraléra pé kí Ọlọ́run dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. (Lúùkù 11:2, 4) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Kristẹni kan tó ti ní ìrètí láti ní ìyè àìnípẹ̀kun tún pàdánù àǹfààní yẹn torí pé wọn ò sin Ọlọ́run mọ́.​—Hébérù 6:4-6; 2 Pétérù 2:20, 21.

 Ibo ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í gba àdúrà tí wọ́n ń pè ní Àdúrà Ẹlẹ́ṣẹ̀?

Èrò àwọn òpìtàn ò ṣọ̀kan lórí bí Àdúrà Ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀. Àwọn kan sọ pé àṣà náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń Ṣàtúnṣe Ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Àwọn míì sì gbà pé ìgbà táwọn ìsìn tuntun bẹ̀rẹ̀ sí í tàn kálẹ̀ láwọn ọdún 1700 àti 1800 ni Àdúrà Ẹlẹ́ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Èyí ó wù kó jẹ́, Bíbélì kò sọ pé ká máa gba “Àdúrà Ẹlẹ́ṣẹ̀,” kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé ká yẹra fún sísọ ohun kan náà lásọtúnsọ nínú àdúrà wa.

a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.