ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Mátíù 6:34—‘Ẹ Má Ṣàníyàn Nípa Ọ̀la’
“Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.”—Mátíù 6:34, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ọla, ọla ni yio ṣe aniyan ara rẹ̀. Buburu ti ojọ tó fún u.”—Mátíù 6:34, Bíbélì Mímọ́.
Ìtumọ̀ Mátíù 6:34
Jésù fi ọ̀rọ̀ yìí dá àwọn tó ń tẹ́tí sí i lójú pé wọn ò ní láti ṣàníyàn jù nípa àwọn ìṣòro tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́la. Kàkà bẹ́ẹ̀, á ṣe wọ́n láǹfààní tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn ìṣòro ìgbésí ayé bí wọ́n ṣe ń yọjú lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.
Jésù ò ní ká má ronú nípa ọ̀la tàbí ká má ṣe ètò kankan fún ọjọ́ iwájú wa. (Òwe 21:5) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé ká yẹra fún àníyàn àṣejù tàbí ìrònú àròjù nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Irú àwọn àníyàn yìí lè mú ká pàdánù ayọ̀ wa, tá ò sì ní lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó yẹ ká ṣe mọ́. Tá a bá ń ṣàníyàn lónìí, ìyẹn ò ní káwọn ìṣòro ọjọ́ iwájú yanjú. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ohun tá à ń ṣàníyàn nípa wọn kì í sábà ṣẹlẹ̀, ó sì lè má burú tó bá a ṣe rò.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Mátíù 6:34
Ara Ìwàásù Jésù Lórí Òkè tó wà ní Mátíù orí 5 sí 7 ni ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ yìí. Nínú ìwàásù yẹn, Jésù ṣàlàyé pé táa bá ń ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ, ìyẹn kò lè mú kí ìgbésí ayé wa dáa sí i tàbí kó mú kí ẹ̀mí wa gùn sí i. (Mátíù 6:27) Ó tún sọ pé tí a bá fi Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wa, kò ní sí ìdí fún wa láti ṣàníyàn àṣejù nípa ọjọ́ ọ̀la. Ọlọ́run ń bójú tó àwọn ewéko àti ẹranko, ó sì dájú pé á bójú tó àìní àwọn tó ń sìn ín náà.—Mátíù 6:25, 26, 28-33.
Ka Mátíù orí 6 pẹ̀lú àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, àwọn atọ́ka etí ìwé àti àwọn àwòrán.