Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Jòhánù 14:27​—“Alaafia Ni Mo Fi Sílẹ̀ Fun Yín”

Jòhánù 14:27​—“Alaafia Ni Mo Fi Sílẹ̀ Fun Yín”

 “Mo fi àlàáfíà sílẹ̀ fún yín; mo fún yín ní àlàáfíà mi. Mi ò fún yín lọ́nà tí ayé gbà ń fúnni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín, kí ìbẹ̀rù má sì mú kí ọkàn yín dà rú.”​—Jòhánù 14:​27, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Alaafia ni mo fi sílẹ̀ fun yín. Alaafia mi ni mo fun yín. Kì í ṣe bí ayé ti í fúnni ni mo fun yín. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín.”​—Jòhánù 14:27 Bíbélì Mímọ́.

Ìtumọ̀ Jòhánù 14:27

 Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí kó lè fi àwọn àpọsítélì rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé tí wọ́n bá níṣòro, kí wọ́n má kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ. Bíi ti Jésù, ọkàn wọn á balẹ̀ tí wọ́n bá gbára lé Ọlọ́run.

 Irú àlàáfíà wo ni Jésù fi sílẹ̀ fún àwọn àpọsítélì rẹ̀? Jésù fún wọn ní àlàáfíà rẹ̀, ìyẹn irú àlàáfíà tí òun náà ní. Ti pé èèyàn ní àlàáfíà yìí kò túmọ̀ sí pé kò ní ìṣòro. (Jòhánù 15:20; 16:33) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fìyà jẹ Jésù lọ́nà àìtọ́, tí wọ́n sì máa pa á, ọ̀kan ẹ̀ balẹ̀. (Lúùkù 23:​27, 28, 32-34; 1 Pétérù 2:23) Ọkàn rẹ̀ balẹ̀ dáadáa torí ó mọ̀ pé Jèhófà Bàbá òun nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì tẹ́wọ́ gba òun. a​—Mátíù 3:​16, 17.

 Jésù fún àwọn àpọsítélì rẹ̀ ní àlàáfíà bó ṣe fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé òun àti Bàbá òun nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n. (Jòhánù 14:23; 15:​9, 10; Róòmù 5:1) Torí wọ́n gbà pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, àlàáfíà tó fún wọn yìí jẹ́ kí wọ́n lè borí ìbẹ̀rù, wọn ò sì kọ́kàn sókè. (Jòhánù 14:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò ní sí níbẹ̀ pẹ̀lú wọn mọ́, ó fi dá wọn lójú pé ẹ̀mí mímọ̀ Ọlọ́run á jẹ́ kí wọ́n ní ìgboyà, kí ọkàn wọn sì balẹ̀. (Jòhánù 14:​25-27) Ní báyìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lè fìgboyà kojú ìṣòro, torí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà wà lẹ́yìn àwọn, á sì ṣe ojúure sáwọn.​—Hébérù 13:6.

 Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn èèyàn sábà máa ń kí ara wọn pé àlàáfíà fún yín o! (Mátíù 10:12) Àmọ́, Jésù ò kàn sọ pé kí wọ́n ní àlàáfíà, ṣe ló fún wọn ní àlàáfíà. Ohun míì tún ni pé, àlàáfíà tí Jésù fún wọn yàtọ̀ pátápátá sí èyí tí ayé b lè fúnni. Ohun tí ayé kà sí àlàáfíà ò ju, ọrọ̀, òkìkí, kéèyàn lẹ́nu láwùjọ, kéèyàn sí lájọṣe pèlú àwọn míì. Amọ́ ipò yòówù ká wà, a lè ní àlàáfíà tí Jésù ń fúnni. Àlàáfíà tá a sì máa gbádùn títí láé ni.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáajú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Jòhánù 14:27

 Alẹ́ ọjọ́ tó kù ọ̀la kí Jésù ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn fún àwọn àpọsítélì rẹ̀. Ó sọ fún wọn ní alẹ́ ọjọ́ yẹn pé òun máa tó fi wọ́n sílẹ̀. (Jòhánù 13:​33, 36) Èyí sì bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ gan-an. (Jòhánù 16:6) Jésù fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kò yẹ kí wọ́n bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí òun bá lọ.

 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn lè fún àwa Kristẹni náà lókun lóde òní. A lè ní àlàáfíà. (2 Tẹsalóníkà 3:16) Nígbà tá a di ọmọlẹ́yìn Jésù, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù àti Jèhófà Bàbá rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà wá. (Kólósè 3:15; 1 Jòhánù 4:16) Torí náà, kò yẹ ká máa kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ tá a bá níṣòro. Kí nìdí? Ìdí ni pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn wa.​—Sáàmù 118:6; Fílípì 4:​6, 7; 2 Pétérù 1:2.

 Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Jòhánù.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?

b Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ayé” ń tọ́ka sí àwọn èèyàn tí ò ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run.