Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

1 Pétérù 5:6, 7—“Ẹ Rẹ Ara Yín Sílẹ̀ Lábẹ́ Ọwọ́ Ọlọrun tí Ó Lágbára, .  .   . Ẹ Kó Gbogbo Ìpayà Yín Tọ̀ Ọ́ Lọ”

1 Pétérù 5:6, 7—“Ẹ Rẹ Ara Yín Sílẹ̀ Lábẹ́ Ọwọ́ Ọlọrun tí Ó Lágbára, .  .   . Ẹ Kó Gbogbo Ìpayà Yín Tọ̀ Ọ́ Lọ”

 “Torí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kó lè gbé yín ga ní àkókò tó yẹ, ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”—1 Pétérù 5:6, 7, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ Ọlọrun tí ó lágbára, yóo gbe yín ga ní àkókò tí ó bá wọ̀. Ẹ kó gbogbo ìpayà yín tọ̀ ọ́ lọ, nítorí ìtọ́jú yín jẹ ẹ́ lógún.”—1 Pétérù 5:6, 7, Yoruba Bible.

Ìtumọ̀ 1 Pétérù 5:6, 7

 Àpọ́sítélì Pétérù sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí kó lè fi dá àwọn Kristẹni lójú pé wọ́n lè sọ gbogbo ìṣòro wọn àtàwọn nǹkan tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn fún Ọlọ́run. Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn tó bá nírẹ̀lẹ̀, ó sì máa bù kún wọn.

 “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run.” Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà ọwọ́ Ọlọ́run, ó sábà máa ń túmọ̀ sí agbára tí Ọlọ́run ní láti gbani là kó sì dáàbò boni. (Ẹ́kísódù 3:19; Diutarónómì 26:8; Ẹ́sírà 8:22) Àwọn Kristẹni lè rẹ ara wọn sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run tí wọ́n bá gbára lé e pátápátá, tí wọ́n sì gbà pé ó níbi tágbára àwọn mọ àti pé àwọn ò lè dá ìṣòro àwọn yanjú. (Òwe 3:5, 6; Fílípì 4:13) Ó dá wọn lójú pé Ọlọ́run lágbára láti ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lákòókò tó tọ́ àti lọ́nà tó dáa jù lọ.—Àìsáyà 41:10.

 “Kó lè gbé yín ga ní àkókò tó yẹ.” Ó dá àwọn tó ń fara da àdánwò lójú pé bópẹ́bóyá Ọlọ́run máa gbé àwọn ga tàbí lédè míì, á san àwọn lẹ́san. Ọlọ́run ò ní jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dojú kọ àdánwò tó kọjá ohun tí wọ́n lè mú mọ́ra. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Kàkà bẹ́ẹ̀, tí wọn ò bá jáwọ́ nínú ṣíṣe rere, ó máa san wọ́n lẹ́san “tí àkókò bá tó” lójú rẹ̀.—Gálátíà 6:9.

 “Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.” Àwa Kristẹni lè kó gbogbo àníyàn wa lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run tá a bá ń fìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà sí i. Ìwé kan sọ pé: “Èrò tí ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí ẹ máa kó gbé jáde ni pé kéèyàn fi gbogbo okun ẹ̀ ju ohun kan sọ nù. Ohun téèyàn sì dìídì ṣe ló túmọ̀ sí.” Tí Kristẹni kan bá kó àníyàn ẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn á jẹ́ kó ní ohun tí Bíbélì pè ní “àlàáfíà Ọlọ́run,” ọkàn ẹ̀ á sì balẹ̀. (Fílípì 4:6, 7) Ó dá a lójú pé Ọlọ́run máa ran òun lọ́wọ́ torí ó mọ̀ pé Ọlọ́run ń bójú tó òun, ó sì lè lo agbára rẹ̀ láti fún òun lókun.—Sáàmù 37:5; 55:22.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé 1 Pétérù 5:6, 7

 Orí karùn-ún ló parí lẹ́tà àkọ́kọ́ tí àpọ́sítélì Pétérù kọ sáwọn Kristẹni. (1 Pétérù 1:1) Bíi tàwa Kristẹni òde òní, àwọn Kristẹni ìgbà yẹn dojú kọ onírúurú àdánwò tó ń dán ìgbàgbọ́ ẹni wò tó lè mú kí wọ́n máa ṣàníyàn. (1 Pétérù 1:6, 7) Ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ yìí ló mú kí Pétérù kọ lẹ́tà tó ń tuni nínú yìí sí wọn ní nǹkan bí ọdún 62 sí 64 Sànmánì Kristẹni.—1 Pétérù 5:12.

 Pétérù wá fi ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú parí lẹ́tà rẹ̀, kó lè fi àwọn tó ń kojú àdánwò torí ìgbàgbọ́ wọn lọ́kàn balẹ̀. Tí wọ́n bá nírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì gbára lé Ọlọ́run, ó dájú pé Ọlọ́run máa fún wọn lókun. (1 Pétérù 5:5-10) Kò sí àní-àní pé àwọn ọ̀rọ̀ Pétérù yìí lè fi àwọn Kristẹni tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí lónìí lọ́kàn balẹ̀.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Pétérù Kìíní.