ORIN 76
Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Rẹ?
-
1. Báwo ló ṣe máa ń rí
tó o bá ń ṣiṣẹ́ ìwàásù,
tó ò ń gbìyànjú láti dé
ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn?
Àwa gbẹ́kẹ̀ lé Jáà,
yóò bù kún iṣẹ́ tá a ṣe,
Torí Ó mọ àwọn tó
jẹ́ ọlọ́kàn tútù.
(ÈGBÈ)
Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún
pé a ti ṣohun tá a lè ṣe.
Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́
tá à ń ṣe lójoojúmọ́.
-
2. Báwo ló ṣe máa ń rí
tó o bá báwọn kan sọ̀rọ̀
tí wọ́n tẹ́tí gbọ́rọ̀ rẹ,
tó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn?
Àwọn mí ì kọ̀ jálẹ̀,
Wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa.
Síbẹ̀, à ń láyọ̀ pé à ń
wàásù orúkọ Jáà.
(ÈGBÈ)
Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún
pé a ti ṣohun tá a lè ṣe.
Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́
tá à ń ṣe lójoojúmọ́.
-
3. Báwo ló ṣe máa ń rí
tó o bá ń ṣiṣẹ́ Jèhófà,
tó fi sí ìkáwọ́ wa,
tó sì ń tì wá lẹ́yìn?
À ń wá àwọn èèyàn
tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́.
À ń sọ̀rọ̀ tútù lẹ́nu
bá a ṣe ń wàásù fún wọn.
(ÈGBÈ)
Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún
pé a ti ṣohun tá a lè ṣe.
Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́
tá à ń ṣe lójoojúmọ́.
(Tún wo Ìṣe 13:48; 1 Tẹs. 2:4; 1 Tím. 1:11.)