ORIN 66
Ẹ Kéde Ìhìn Rere Náà
-
1. Tipẹ́tipẹ́ laráyé ti jogún ẹ̀ṣẹ̀,
Àmọ́ Jèhófà ṣàánú wa, ó nífẹ̀ẹ́ wa.
Ó pinnu láti f’Ọmọ rẹ̀ ṣe Ọba wa,
Àmọ́ ó kọ́kọ́ ṣe ọ̀rọ̀ náà láṣìírí.
Ó ti wá fi àṣírí náà hàn wá báyìí.
Láìpẹ́, Ọmọ rẹ̀ máa bẹ̀rẹ̀ sí í
jọba ayé.
Jáà ti yan àwọn ẹni àmì òróró
Tó máa bá Jésù Ọmọ rẹ̀ jọba lọ́run.
-
2. Jáà ti ṣètò pé tó bá d’àkókò òpin,
A máa kéde ìhìn rere yìí fáráyé.
Àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ń fayọ̀ ràn wá lọ́wọ́;
Wọ́n ń tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ńwàásù òtítọ́.
Iṣẹ́ pàtàkì ló já lé wa léjìká:
Ká máa yìn ọ́, ká jẹ́
kórúkọ rẹ di mímọ́.
Ọlá ńlá ló jẹ́ bá a ṣe ń jẹ́ orúkọ mọ́ọ.
Tayọ̀tayọ̀ la ó máa ròyìn rẹ fáráyé.
(Tún wo Máàkù 4:11; Ìṣe 5:31; 1 Kọ́r. 2:1, 7.)