ORIN 61
Ẹ Tẹ̀ Síwájú, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí
-
1. Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pinnu
Láti máa fìgboyà wàásù lákòókò yìí.
Èṣù ń ta kò wá, ó sì ńgbógun.
Àmọ́, a dúró ṣinṣin ti Jèhófà.
(ÈGBÈ)
Ẹ tẹ̀ síwájú, Ẹlẹ́rìí onígboyà.
Ẹ máa yọ̀ pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́.
Ẹ sọ fáráyé pé Párádísè dé tán.
Ìjọba Ọlọ́run yóò bù kún wa.
-
2. Ìránṣẹ́ Jáà, má ṣe gbé ayé fàájì.
Ṣọ́ra fún ìfẹ́ ayé, má ṣe bíi tiwọn.
Má jẹ́ kí wọ́n kó èérí bá ọ.
Jẹ́ adúróṣinṣin títí dé òpin.
(ÈGBÈ)
Ẹ tẹ̀ síwájú, Ẹlẹ́rìí onígboyà.
Ẹ máa yọ̀ pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́.
Ẹ sọ fáráyé pé Párádísè dé tán.
Ìjọba Ọlọ́run yóò bù kún wa.
-
3. Wọ́n ń pẹ̀gàn Ọlọ́run àt’Ìjọba rẹ̀.
Wọ́n ń bà á lórúkọ jẹ́, wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa.
Ká jẹ́ kórúkọ rẹ̀ di mímọ́.
Ẹ jẹ́ ká kéde rẹ̀ fún gbogbo ayé.
(ÈGBÈ)
Ẹ tẹ̀ síwájú, Ẹlẹ́rìí onígboyà.
Ẹ máa yọ̀ pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́.
Ẹ sọ fáráyé pé Párádísè dé tán.
Ìjọba Ọlọ́run yóò bù kún wa.
(Tún wo Ẹ́kís. 9:16; Fílí. 1:7; 2 Tím. 2:3, 4; Jém. 1:27.)