ORIN 2
Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
-
1. Ọlọ́run òtítọ́,
Jèhófà lorúkọ rẹ.
Ìwọ nìkan lo ṣẹ̀dá
Gbogbo ohun tó wà.
Àǹfààní ńlá la ní
Pé a jẹ́ ènìyàn rẹ.
Nínú gbogbo aráyé,
À ń jẹ́ kógo rẹ tàn.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, Jèhófà,
Kò s’Ọ́lọ́run mìíràn
Tó dà bíi rẹ lábẹ́ ilẹ̀,
Lọ́run tàbí láyé.
Ọlọ́run Olódùmarè;
Gbogbo ayé yóò gbọ́.
Jèhófà, Jèhófà,
Ìwọ nìkan ṣoṣo la ní.
-
2. Alèwí, Alèṣe;
O mú kí a lè máa ṣe
Ohunkóhun tí o fẹ́,
Ká sì ṣe é bó o ṣe fẹ́ẹ.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Ni orúkọ tó o fún wa.
Ọlá ńlá ló sì jẹ́ pé
Aráyé ń pè wá bẹ́ẹ̀.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, Jèhófà,
Kò s’Ọ́lọ́run mìíràn
Tó dà bí rẹ lábẹ́ ilẹ̀,
Lọ́run tàbí láyé.
Ọlọ́run Olódùmarè;
Gbogbo ayé yóò gbọ́.
Jèhófà, Jèhófà,
Ìwọ nìkan ṣoṣo la ní.
(Tún wo 2 Kíró. 6:14; Sm. 72:19; Àìsá. 42:8.)