ORIN 160
“Ìhìn Rere”!
1. Ìròyìn ayọ̀ ti dé.
Ògo f’Ọlọ́run.
A bí Olùgbàlà kan fún wa.
Òmìnira dé.
A ti wá nírètí!
(ÈGBÈ)
Ìròyìn ayọ̀!
Wàásù rẹ̀ fáyé.
Ẹ yin Jèhófà!
Ó tan ìmọ́lẹ̀
òtítọ́ fún wa.
Wàásù pé Jésù
Lọ̀nà, òótọ́, ìyè.
2. Yóò mú kí àlàáfíà wà
Ní gbogbo ayé.
Ipasẹ̀ rẹ̀ la máa fi ríyè.
Ìjọba Jésù
Máa dúró títí láé.
(ÈGBÈ)
Ìròyìn ayọ̀!
Wàásù rẹ̀ fáyé.
Ẹ yin Jèhófà!
Ó tan ìmọ́lẹ̀
òtítọ́ fún wa.
Wàásù pé Jésù
Lọ̀nà, òótọ́, ìyè.
(ÈGBÈ)
Ìròyìn ayọ̀!
Wàásù rẹ̀ fáyé.
Ẹ yin Jèhófà!
Ó tan ìmọ́lẹ̀
òtítọ́ fún wa.
Wàásù pé Jésù
Lọ̀nà, òótọ́, ìyè.
(Tún wo Mát. 24:14; Jòh. 8:12; 14:6; Àìsá. 32:1; 61:2.)