ORIN 16
Ẹ Yin Jáà Nítorí Ọmọ Rẹ̀ Tó Fòróró Yàn
-
1. Jèhófà ti yan Ọmọ rẹ̀
Láti ṣàkóso ayé,
Kí ìfẹ́ Rẹ̀ lè ṣẹ ní ayé;
Ọba olódodo ló jẹ́.
(ÈGBÈ)
Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀,
ẹ̀yin tó ń tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀;
Gbogbo olódodo, ẹ yin Jésù,
Ọba tí Ọlọ́run yàn.
Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀,
tó ń jọba nísàálú ọ̀run.
Ó ń gbórúkọ mímọ́ Ọlọ́run ga
Pẹ̀lú agbára ńlá rẹ̀.
-
2. Àwọn arákùnrin Kristi
T’Ọ́lọ́run sọ d’àtúnbí,
Wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù
Láti sọ ayé di tuntun.
(ÈGBÈ)
Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀,
ẹ̀yin tó ń tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀;
Gbogbo olódodo, ẹ yin Jésù,
Ọba tí Ọlọ́run yàn.
Ẹ yin Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀,
tó ń jọba nísàálú ọ̀run.
Ó ń gbórúkọ mímọ́ Ọlọ́run ga
Pẹ̀lú agbára ńlá rẹ̀.
(Tún wo Òwe 29:4; Àìsá. 66:7, 8; Jòh. 10:4; Ìfi. 5:9, 10.)