ORIN 153
Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà
1. Ìbẹ̀rù ti bò mí—
Ìdààmú gbọkàn mi.
Ọlọ́run jọ̀ọ́ fi mí mọ̀nà;
Mo mọ̀ pó o máa gbà mí.
Ìṣòro pọ̀ láyé,
Ṣùgbọ́n mo gbà gbọ́ pé:
Atóófaratì mà ni ọ́;
Ayé mi dọwọ́ rẹ.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, fún mi nígbàgbọ́
Kí n lè máa rántí pé
Àwọn ọ̀tá kò lè borí wa.
Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n nígboyà.
Kí n sì ṣọkàn akin;
Kí n fara dà á dópin.
Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà;
Ìwọ ni aṣẹ́gun.
2. Tí ìbẹ̀rù bá dé.
Ó ń múni rẹ̀wẹ̀sì.
Ìwọ làpáta ààbò mi;
O kì í jáni kulẹ̀.
Jẹ́ kí n ní ìgboyà,
Kí n má sì ṣe jáyà.
Bó ti wù kí ‘ṣòro le tó—
Tìrẹ ni màá ṣe láé.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, fún mi nígbàgbọ́
Kí n lè máa rántí pé
Àwọn ọ̀tá kò lè borí wa.
Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n nígboyà.
Kí n sì ṣọkàn akin;
Kí n fara dà á dópin.
Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà;
Ìwọ ni aṣẹ́gun.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, fún mi nígbàgbọ́
Kí n lè máa rántí pé
Àwọn ọ̀tá kò lè borí wa.
Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n nígboyà.
Kí n sì ṣọkàn akin;
Kí n fara dà á dópin.
Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà;
Ìwọ ni aṣẹ́gun.
Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà;
Ìwọ ni aṣẹ́gun.