ORIN 140
Ìyè Àìnípẹ̀kun Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín!
-
1. Fi ojú inú rẹ wo
Àwọn tó ń gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀.
Kò sẹ́kún mọ́; wọ́n ń láyọ̀.
Ìrora kò sí mọ́.
(ÈGBÈ)
Jẹ́ ká fayọ̀ kọrin!
Ayé tuntun dé tán.
Títí láéláé la ó máa gbé
Inú ayé tuntun.
-
2. A ò ní máa darúgbó mọ́.
Àlàáfíà ni yóò jọba.
Wàhálà kò ní sí mọ́.
Kò ní síbẹ̀rù mọ́.
(ÈGBÈ)
Jẹ́ ká fayọ̀ kọrin!
Ayé tuntun dé tán.
Títí láéláé la ó máa gbé
Inú ayé tuntun.
-
3. A ó gbádùn Párádísè.
Ògo Jáà yóò máa tàn yòò.
Gbogbo ọjọ́ ayé wa
La ó máa kọrin ìyìn.
(ÈGBÈ)
Jẹ́ ká fayọ̀ kọrin!
Ayé tuntun dé tán.
Títí láéláé la ó máa gbé
Inú ayé tuntun.
(Tún wo Jóòbù 33:25; Sm. 72:7; Ìfi. 21:4.)