Privacy Settings

To provide you with the best possible experience, we use cookies and similar technologies. Some cookies are necessary to make our website work and cannot be refused. You can accept or decline the use of additional cookies, which we use only to improve your experience. None of this data will ever be sold or used for marketing. To learn more, read the Global Policy on Use of Cookies and Similar Technologies. You can customize your settings at any time by going to Privacy Settings.

Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 133

Sin Jèhófà Nígbà Ọ̀dọ́

Sin Jèhófà Nígbà Ọ̀dọ́

(Oníwàásù 12:1)

  1. 1. Jèhófà fẹ́ràn àwa ọ̀dọ́ gan-an.

    Tọkàntọkàn sì la fi ń jọ́sìn rẹ̀.

    Ó dájú pé ó ń fiyè síṣẹ́ wa,

    Yóò sì bù kún wa jálẹ̀ ayé wa.

  2. 2. Àwa ọ̀dọ́ ń bọ̀wọ̀ fún òbí wa,

    A sì ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.

    Èyí ń jẹ́ kí inú wọn dùn sí wa,

    A sì túbọ̀ ń sún mọ́ Jáà, Ọ̀rẹ́ wa.

  3. 3. Káwa ọ̀dọ́ rántí Ọlọ́run wa.

    Kí òtítọ́ máa jinlẹ̀ lọ́kàn wa.

    Tá a bá fi ayé wa sin Jèhófà,

    Inú rẹ̀ yóò dùn, yóò sì bù kún wa.

 

Sin Jèhófà Nígbà Ọ̀dọ́