ORIN 129
A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó
-
1. Jésù Aṣáájú
Wa fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀.
Ó nífaradà,
Ìrètí tó ní fún un láyọ̀.
Ó ń retí bí ‘lérí
Bàbá rẹ̀ yóò ṣe ṣẹ.
(ÈGBÈ)
Ẹ jẹ́ ká máa fara dà á,
Ká fìwà jọ Jésù.
Jèhófà wà pẹ̀lú wa,
Ká máa fara dà á títí dé òpin.
-
2. Ọ̀pọ̀ àdánwò
Là ńdojú kọ bá a ṣe ńsin Jáà.
Ká máa fara dà á;
Ayọ̀ ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Ká má ṣe rẹ̀wẹ̀sì,
Ìgbà ọ̀tun dé tán.
(ÈGBÈ)
Ẹ jẹ́ ká máa fara dà á,
Ká fìwà jọ Jésù.
Jèhófà wà pẹ̀lú wa,
Ká máa fara dà á títí dé òpin.
-
3. A fẹ́ máa bá a lọ
Láti fara da àdánwò.
Ká máa fòótọ́ sìn,
Ká má bẹ̀rù, ká má fòyà.
Ká jẹ́ olótìítọ́;
Ká fara dà á dópin.
(ÈGBÈ)
Ẹ jẹ́ ká máa fara dà á,
Ká fìwà jọ Jésù.
Jèhófà wà pẹ̀lú wa,
Ká máa fara dà á títí dé òpin.
(Tún wo Ìṣe 20:19, 20; Jém. 1:12; 1 Pét. 4:12-14.)