ORIN 12
Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá
-
1. Ògo àtìyìn yẹ ọ́, Jèhófà,
Ẹniire tó ń ṣòdodo
Ní gbogbo ọ̀nà lo jẹ́.
Agbára, ọgbọ́n àtìfẹ́ rẹ pọ̀,
Ọlọ́run ayérayé.
-
2. Bàbá, àánú rẹ máa ńtù wá lára.
O máa ń gbọ́ àdúrà wa
Báa tilẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Ò ń gbẹ́mìí wa ró, o sì tún ńkọ́ wa;
Atóófaratì ni ọ́!
-
3. Àwọn ẹ̀dá lọ́run àti láyé,
Wọ́n ń forin yìn ọ́ lógo;
Àwa náà yóò máa yìn ọ́.
Atóbilọ́lá, jọ̀ọ́ gba ìyìn wa.
Tọkàntọkàn là ń yìn ọ́.
(Tún wo Diu. 32:4; Òwe 16:12; Mát. 6:10; Ìfi. 4:11.)