ORIN 108
Ìfẹ́ Ọlọ́run Tí Kì Í Yẹ̀
-
1. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.
Ẹ̀rí fi hàn pó nífẹ̀ẹ́ wa.
Ó fi Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo
Ṣe ìràpadà fáráyé
Ká lè níyè àìnípẹ̀kun,
Ká sì láyọ̀ títí ayé.
(ÈGBÈ)
Gbogbo ẹ̀yin tóùngbẹ ń gbẹ,
Ẹ wá mumi ‘yè lọ́fẹ̀ẹ́.
Kẹ́ ẹ mu ún, kọ́kàn yín balẹ̀;
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín.
-
2. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.
Gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́rìí sí i.
Ó gbé Ọmọ rẹ̀ gorí ‘tẹ́.
Ó ti sọ ọ́ di ọba lọ́run.
Ìfẹ́ Ọlọ́run ti wá ṣẹ,
’Jọba náà ti fìdí múlẹ̀!
(ÈGBÈ)
Gbogbo ẹ̀yin tóùngbẹ ń gbẹ,
Ẹ wá mumi ‘yè lọ́fẹ̀ẹ́.
Kẹ́ ẹ mu ún, kọ́kàn yín balẹ̀;
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín.
-
3. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.
Kẹ́mìí rẹ̀ mú ká fìfẹ́ hàn,
Ká sì kọ́ ọlọ́kàn tútù
Kí wọ́n lè pa òfin Jáà mọ́.
Ká máa fi ìgboyà wàásù,
Ká sì níbẹ̀rù Ọlọ́run.
(ÈGBÈ)
Gbogbo ẹ̀yin tóùngbẹ ń gbẹ,
Ẹ wá mumi ‘yè lọ́fẹ̀ẹ́.
Kẹ́ ẹ mu ún, kọ́kàn yín balẹ̀;
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín.