Ọ̀rọ̀ Rẹ Wà Títí Láé
Wà á jáde:
1. Jáà ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé;
Wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gan-an.
Wọ́n ń fọpẹ́ f’Ọ́lọ́run wọn
Torí ìfẹ́ tó ní sí wọn.
O wá dá wọn lọ́lá;
Wọ́n ń sọ̀rọ̀ Ìjọba rẹ.
Ọ̀rọ̀ tó wúlò dòní,
Òtítọ́ tó ń fọ̀nà hàn wá.
Wọ́n fẹ́ ọ tọkàntọkàn,
Wọ́n ṣe gbogbo ‘hun t’ọ́n lè ṣe.
Ìwọ yàn wọ́n kí wọ́n k’Ọ́rọ̀ rẹ,
Kí aráyé bàa lè mọ̀ ọ́.
(ÈGBÈ)
Ọ̀rọ̀ rẹ wà títí láé,
Bẹ́ẹ̀ sì lọ̀rọ̀ rẹ jinlẹ̀.
Ìhìn rere rẹ máa ń mú ara tu èèyàn,
Ọ̀rọ̀ rẹ ni mo sì ń fẹ́ pa mọ́.
2. O, bí àwọn ọ̀tá tiẹ̀ ń gbógun,
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń gbilẹ̀ sí i.
Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ
Kò bẹ̀rù, wọ́n ń sìn ọ́ nìṣó.
‘Gbà tọ́tàá gbẹ́sẹ̀ lé Bíbélì,
Wọn kò bẹ̀rù bó já síkú.
Ìgbàgbọ́ wọn jinlẹ̀, ẹ̀rí wọn lágbára,
Wọn kò yọ̀rọ̀ rẹ kan kúrò.
(ÈGBÈ)
Bẹ́ẹ̀ ni, Ọ̀rọ̀ rẹ wà títí láé,
Bẹ́ẹ̀ sì lọ̀rọ̀ rẹ jinlẹ̀.
Ìhìn rere rẹ máa ń mú ara tu èèyàn,
Ọ̀rọ̀ rẹ ni mo sì ń fẹ́ pa mọ́.
3.O jẹ́ ká morúkọ rẹ, Jèhófà.
Ó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ.
Orúkọ àt’Ọ̀rọ̀ rẹ
Kò ní pa rẹ́ láé,
A óò máa yìn ọ́ títí ayé.
(ÈGBÈ)
Ọ̀rọ̀ rẹ máa wà títí láé,
Bẹ́ẹ̀ sì lọ̀rọ̀ rẹ jinlẹ̀.
Ìhìn rere rẹ máa ń mú ara tu èèyàn,
Ọ̀rọ̀ rẹ ni mo sì ń fẹ́ pa mọ́
Títí ayé.