Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù
Wà á jáde:
1. Ọ̀pọ̀ ìpinnu là ń ṣe lójoojúmọ́.
Ó yẹ ká máa fọgbọ́n lo àkókò wa.
A máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa,
Àmọ́ nǹkan míì wà tó tún ṣe pàtàkì jù.
(ÈGBÈ)
A gbọ́dọ̀ wáyè fóhun tó ṣe pàtàkì jù—
Gbàdúrà, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́.
Sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn gan-an ló dára jù.
Fàkókò rẹ ṣohun gidi.
Máa ronú nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ.
Má ṣe gbàgbé ohun tó ṣe pàtàkì jù.
2. Àtijẹ-àtimu, lè má rọrùn.
Àmọ́ èyí lè fa ìpínyà ọkàn.
Ká máa wáyè fún ìdílé wa.
Tá a bá fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́, tá a fẹ́ bójú tó wọn—
(ÈGBÈ)
A gbọ́dọ̀ wáyè fóhun tó ṣe pàtàkì jù—
Gbàdúrà, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́.
Sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn gan-an ló dára jù..
Fàkókò rẹ ṣohun gidi.
Máa ronú nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ.
Má ṣe gbàgbé ohun tó ṣe pàtàkì jù.
(ÈGBÈ)
A gbọ́dọ̀ wáyè fóhun tó ṣe pàtàkì jù—
Gbàdúrà, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́.
Sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn gan-an ló dára jù.
Fàkókò rẹ ṣohun gidi.
Máa ronú nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ.
Má ṣe gbàgbé ohun tó ṣe pàtàkì jù.