“Fi Àwọn Ohun Ìní Rẹ Tí Ó Níye Lórí Bọlá fún Jèhófà”
Wà á jáde:
1. Kò sóhun tí Jèhófà kò ní tá a fẹ́ fún un.
Òun ló dá ohun gbogbo.
Kí ni màá fún un tàbí kí n fayé mi ṣe
Lọ́nà tí màá fi múnú rẹ̀ dùn?
Mo mohun tí màá ṣe lójoojúmọ́ ayé mi
Mo ti wá pinnu pé:
(ÈGBÈ)
Ohun tó dára jù ni màá fún ọ, Jèhófà.
Jèhófà, ìwọ ni màá fọjọ́ ayé mi sìn.
Bó ti wù kó lé tó,
Màá fohun tí mo ní bọlá fún ọ.
2. O dá wa sáyé torí ‘fẹ́ rẹ fún wa,
Èyí sì máa ń mú inú mi dùn.
Kí ni ń bà tún ṣe láti bọlá fún ọ?
Màá fohun mo ní bọlá fún ọ.
Mo mohun tí màá ṣe lójoojúmọ́ ayé mi
Mo ti mohun tí màá ṣe:
(ÈGBÈ)
Ohun tó dára jù ni màá fún ọ, Jèhófà.
Jèhófà, ìwọ ni màá fọjọ́ ayé mi sìn.
Bó ti wù kó lé tó,
Màá fohun tí mo ní bọlá fún ọ.