“Kò Ní Pẹ́ Rárá!” (Orin Àpéjọ Agbègbè 2023)
Wà á jáde:
1. Àwòyanu ni, iṣẹ́ rẹ Baba,
Torí pó o fẹ́ wa, lo ṣe dá gbogbo wọn.
Ṣụ̀gbọ́n ìṣòro ti pọ̀ jù láyé; a mọ̀ pé láìpẹ́,
Wàá yanjú gbogbo rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Jèhófà Baba wa, jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.
Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kó sú wa.
À ń retí ọjọ́ náà, táyé tuntun máa dé.
Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù.
Ká fìwà jọ ọ́.
2. Téèyàn wa bá kú, ó máa ń dùn wá gan-an.
O ṣèlérí pé wàá jí òkú dìde.
A mọ̀ dájú pé ọ̀rọ̀ rẹ máa ṣẹ.
Alèwílèṣe, jọ̀ọ́ jẹ́ ká ní sùúrù.
(ÈGBÈ)
Jèhófà Baba wa, jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.
Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kó sú wa.
À ń retí ọjọ́ náà, táyé tuntun máa dé.
Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù.
Ká fìwà jọ ọ́.
3. Ikú ẹlẹ́ṣẹ̀ kò wù ọ́ Baba.
O fẹ́ kí gbogbo èèyàn wá dọ̀rẹ̀ẹ́ rẹ.
O rán wa jáde, ká wàásù fún wọn,
Káwa àtàwọn lè wà láàyè láéláé.
(ÈGBÈ)
Jèhófà Baba wa, jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.
Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kó sú wa.
À ń retí ọjọ́ náà, táyé tuntun máa dé.
Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù.
Ká fìwà jọ ọ́.
Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù!
(Tún wo Kól. 1:11.)