A Ò Ní Dẹwọ́
Wà á jáde:
1. Ọ̀pọ̀ ni kò mọ̀ pé
Báyé yìí ṣe ń burú sí i,
Lọjọ́ Jèhófà náà ń sún mọ́lé.
Aráyé gbọ́dọ̀ mọ̀.
2. Ó yẹ ká fìgboyà
Wàásù kí wọ́n lè ríyè.
Ká bẹ Jèhófà fún ẹ̀mí rẹ̀.
Ká lè sàṣeyọrí.
ÈGBÈ
Ká máa fìtara wàásù
Àkókò ti dín kù
Ká jẹ́ onígboyà
Ká tan ìmọ́lẹ̀ òótọ́
Ká ṣe ọkàn akin
Ká jẹ́ onígboyà
Ká má bẹ̀rù
3. Ká má ṣe gbàgbé pé
Òpin ayé yìí dé tán.
Àkókò yìí ló yẹ ká kọ́ wọn
Kí wọ́n lè rí òótọ́.
(ÈGBÈ)
Ká máa fìtara wàásù
Àkókò ti dín kù,
Ká jẹ́ onígboyà.
Ká tan ìmọ́lè òótọ́.
Ká ṣe ọkàn akin.
Ká jẹ́ onígboyà.
Ká má bẹ̀rù.
(ÀSOPỌ̀)
Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú ọkàn wa
Kí wọ́n lè ṣàtúnṣe kó tó pẹ́ jù.
Wọ́n gbọ́dọ̀ gbọ́.
(ÈGBÈ)
Ká máa fìtara wàásù
Àkókò ti dín kù
Ká jẹ́ onígboyà
Ká tan ìmọ́lẹ̀ òótọ́
Ká ṣe ọkàn akin
Ká jẹ́ onígboyà.
Ká má bẹ̀rù
Ká má bẹ̀rù
Ká má bẹ̀rù