Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Bá A Ṣe Pèsè Ìrànwọ́ Lọ́dún 2021—A Ò Pa Àwọn Arákùnrin Àtàwọn Arábìnrin Wa Tì

Bá A Ṣe Pèsè Ìrànwọ́ Lọ́dún 2021—A Ò Pa Àwọn Arákùnrin Àtàwọn Arábìnrin Wa Tì

JANUARY 1, 2022

 Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2021, a àrùn Corona fojú àwọn èèyàn rí màbo kárí ayé. Bá a ṣe ṣàlàyé nínú àpilẹ̀kọ náà “A Ṣètò Ìrànwọ́ Fáwọn Ará Kárí Ayé Nígbà Àjàkálẹ̀ Àrùn,” a ti ná ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù owó dọ́là b láti fi ṣèrànwọ́ lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn yìí, a sì ti yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti àádọ́ta (950).

 Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn yìí ṣì ń jà ràn-ìn, àwọn àjálù míì lóríṣiríṣi tún fojú àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin rí màbo kárí ayé. Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká ná nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ owó dọ́là láfikún sáwọn ohun tá a ti fi ṣèrànwọ́ torí àjàkálẹ̀ àrùn Corona, ká lè bójú tó àwọn àjálù míì tó lé ní igba (200) tó ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn àjálù méjì kan wáyé, ẹ kíyè sí bá a ṣe ná àwọn owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètọrẹ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù náà ṣẹlẹ̀ sí.

Òkè Nyiragongo Bú Gbàù

 Ní May 22, 2021, òkè ayọnáyèéfín kan tó ń jẹ́ Nyiragongo lórílẹ̀-èdè Kóńgò bú gbàù. Ohun tó tú jáde nínú òkè náà ba ọ̀pọ̀ ilé àti ilé ìwé jẹ́, títí kan ibi tí wọ́n tọ́jú omi táwọn aráàlú ń lò sí. Àmọ́, ohun tó tú jáde yẹn nìkan kọ́ ló wu ẹ̀mí àwọn èèyàn léwu. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni èéfín tó lè pani lára fi bo ìlú Goma, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé. Ohun tó ju ìdajì àwọn tó ń gbé ìlú náà ni wọ́n ní láti fibẹ̀ sílẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló sì sá kúrò nílùú, kódà àwọn míì sọdá ibodè lọ sórílẹ̀-èdè Rùwáńdà.

Ní Gbọ̀ngàn ìjọba kan, ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù pèsè oúnjẹ tó gbóná fún àwọn ará

 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún wà lára àwọn tó kúrò ní agbègbè náà. Òkè tó bú gbàù yẹn ba ilé àwọn kan jẹ́, wọ́n sì jí ẹrù àwọn míì kó nígbà tí wọ́n sá kúrò ní agbègbè náà. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà àti Kóńgò ló ṣètò ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù náà ṣẹlẹ̀ sí. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Kóńgò (Kinshasa) sọ nípa ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ tó ń ṣèrànwọ́ pé: “Kí ìjọba tiẹ̀ tó sọ pé kí àwọn èèyàn kúrò nílùú ni ìgbìmọ̀ náà ti ń pín oúnjẹ, omi, ohun táwọn èèyàn lè fi sùn àti aṣọ láìka ti pé nǹkan ò fara rọ.” Àwọn ará wa tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì (2000) kóra jọ ní ìlú kan, ìgbìmọ̀ yẹn wá ṣètò àwọn àgọ́ táwọn ará lè máa sùn sí, wọ́n pín ìbòmú, wọ́n sì ṣàlàyé ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n má bàa kó àrùn Corona àti cholera.

Wọ́n ń wọn oúnjẹ tí wọ́n fẹ́ pín fún àwọn ará tí àjálù dé bá

 Láàárín oṣù mẹ́ta tí àjálù náà ṣẹlẹ̀, àwọn ará wa pín nǹkan tó ju tọ́ọ̀nù mẹ́fà ìrẹsì, tọ́ọ̀nù mẹ́fà ìyẹ̀fun, tọ́ọ̀nù mẹ́ta òróró àti omi tọ́ọ̀nù mẹ́ta. Ká lè ṣọ́wó ná, ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò pé ká ra oúnjẹ tó pọ̀ gan-an lágbègbè yẹn dípò ká rà á látòkè òkun.

 Arábìnrin kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ba ilé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ jẹ́ sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú ká rẹ̀wẹ̀sì, ó sì bà wá nínú jẹ́ gan-an. Àmọ́ ìdílé rẹ̀ rí ìrànlọ́wọ́ gbà nípa tara àti nípa tẹ̀mí, èyí sì mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Ó wá sọ pé: “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a ṣì ní àwọn ohun tá a nílò. A ti wá rí i pé Jèhófà ló ń bá wa gbé ẹrù wa, ìyẹn ló jẹ́ kó rọrùn fún wa láti fara dà á.”

Ọrọ̀ Ajé Dẹnu Kọlẹ̀ Ní Fẹnẹsúélà

 Ọ̀pọ̀ ọdún ni ọrọ̀ ajé ti fi dẹnu kọlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà. Onírúurú nǹkan làwọn ará wa ń fara dà, bí ipò nǹkan tó le gan-an, àìtó oúnjẹ àti ìwà ipá tó ń pọ̀ sí i. Àmọ́, ètò Ọlọ́run ò pa wọ́n tì.

Wọ́n ń kó àwọn àpò ìrẹsì tí wọ́n fẹ́ kó lọ sí àwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà sínú mọ́tò

 Láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, a ná ohun tó ju mílíọ̀nù kan ààbọ̀ owó dọ́là láti ra oúnjẹ àti ọṣẹ fáwọn ìdílé tó jẹ́ aláìní. Ẹ̀ka ọ́fíìsì Fẹnẹsúélà ròyìn pé: “Kò rọrùn rárá láti máa kó oúnjẹ tó tó àádóje (130) tọ́ọ̀nù lọ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin orílẹ̀-èdè yìí. Kò tán síbẹ̀ o, a tún máa ń ṣètò bó ṣe máa dé ọ̀dọ̀ àwọn ará tó nílò rẹ̀.” Kí ohunkóhun má bàa ṣòfò, àwọn ará máa ń fi oúnjẹ tí kò ní tètè bà jẹ́ ránṣẹ́. Wọ́n fi kún un pé: “A máa ń kíyè sí àsìkò tí oúnjẹ kan bá jáde tí owó ẹ̀ sì wálẹ̀, àá wá rà á lọ́pọ̀. A sì máa ń fi ránṣẹ́ lọ́nà tí ò ní náwa lówó jù.”

Torí pé kò sí epo, kò sì sí ọkọ̀ lárọ̀ọ́wọ́tó, àwọn ará tó jẹ́ ọ̀dọ́ ń fi kẹ̀kẹ́ rìnrìn àjò kìlómítà méjìdínlógún (18) ní àlọ àti àbọ̀ láti kó oúnjẹ lọ fún àwọn ará ìjọ wọn

 Arákùnrin Leonel tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ní Fẹnẹsúélà nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ẹ̀. Ó sọ pé, “Iṣẹ́ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀. Bí mo ṣe ń ṣe é, ṣe ló ń tù mí nínú pàápàá lẹ́yìn tí àrùn Corona gbẹ̀mí ìyàwó mi. Bí mo ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó wà nínú ìṣòro yìí jẹ́ kí n rí i pé èmi náà wúlò. Mo ti wá ń fojú ara mi rí bí Jèhófà ṣe ń mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ pé òun ò ní fi àwọn èèyàn òun silẹ̀.”

 Arákùnrin kan tóun náà ti fìgbà kan rí wà nínú ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ jàǹfààní nínú ìrànwọ́ tí wọ́n ṣe yìí. Ó sọ pé: “Èmi ló yí kàn lọ́tẹ̀ yìí, kì í ṣe àwọn nǹkan tara tá a nílò nìkan ni wọ́n pèsè fún wa, àwọn ará yẹn tún fi èmi àti ìyàwó mi lọ́kàn balẹ̀, wọ́n bójú tó wa, wọ́n tù wá nínú, wọ́n sì tún fún wa níṣìírí.”

 Àwọn àjálù kan máa ń ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Síbẹ̀, ètò Ọlọ́run máa ń pèsè ìrànwọ́ fún àwọn ará wa láìjáfara, ọrẹ tẹ́ ẹ fi ń ti iṣẹ́ kárí ayé lẹ́yìn ló ń mú kí èyí ṣeé ṣe. Ẹ máa rí díẹ̀ lára ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà ṣètọrẹ lórí Ìkànnì donate.jw.org. A mọrírì ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín gan-an.

a Ọdún iṣẹ́ ìsìn 2021 bẹ̀rẹ̀ ní September 1, 2020, ó sì parí ní August 31, 2021.

b Owó dọ́là ti Amẹ́ríkà la lò nínú àpilẹ̀kọ yìí.