Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ṣé Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lè Pawọ́ Pọ̀ Yanjú Ìṣòro Ojú Ọjọ́ Tó Ń Burú Sí I?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Lọ́jọ́ Sunday, November 20, 2022, ìpàdé tí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ṣe lórí ọ̀rọ̀ ojú ọjọ́ tó ń burú sí i parí. Nípàdé náà, wọ́n fẹnu kò pé àwọn á máa dáwó fáwọn orílẹ̀-èdè tí àjálù ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀ torí ojú ọjọ́ tó ń burú sí i. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìpinnu tí wọ́n fẹnu kò lé lórí yìí dáa, àwọn kan mọ̀ pé ìyẹn ò lè yanjú ìṣòro náà.
António Guterres tó jẹ́ akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ ní November 19, 2022 pé: “Ó dáa bí wọ́n ṣe fẹnu kò pé wọ́n á máa dáwó láti bójú tó ìṣòro yìí, síbẹ̀, ìyẹn ò lè yanjú wàhálà tó wà nílẹ̀ . . . Nǹkan ti bà jẹ́ gan-an láyé yìí.”
Mary Robinson tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Ireland àti Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn sọ ní November 20, 2022 pé: “Wàhálà ń bọ̀ láyé yìí torí ọ̀rọ̀ ojú ọjọ́ tó ń burú sí i.”
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ń bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ayé wa yìí lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, ṣé àwọn orílẹ̀-èdè lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti yanjú ìṣòro ojú ọjọ́ tó ń burú sí i yìí? Kí ni Bíbélì sọ?
Ṣé àwọn orílẹ̀-èdè lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí?
Bó ti wù káwọn orílẹ̀-èdè sapá tó, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àṣeyọrí tí wọ́n máa ṣe láti yanjú ìṣòro ojú ọjọ́ ò ní tó nǹkan. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí méjì tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀:
“Ohun tó ti wọ́, a kò lè mú un tọ́.”—Oníwàásù 1:15.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ìjọba èèyàn ò lè ṣàṣeyọrí torí pé Ọlọ́run ò dá àwa èèyàn láti máa ṣàkóso ara wa. (Jeremáyà 10:23) Kódà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá tiẹ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀, wọn ò lè yanjú àwọn ìṣòro ayé yìí bó ti wù kí wọ́n sapá tó.
‘Torí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á jẹ́ kìígbọ́-kìígbà.’—2 Tímótì 3:2, 3.
Ohun tó túmọ̀ sí: Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwà ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ò ní dáa rárá. Bí àpẹẹrẹ, tara wọn nìkan ni wọ́n á mọ̀, wọn ò sì ní fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn míì láti tún nǹkan ṣe. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn.
Ohun tó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀
Òótọ́ kan ni pé ohun yòówù kí ìjọba èèyàn ṣe, ayé yìí ṣì máa dáa. Ìdí ni pé, Ọlọ́run ti yan Ọba kan tó dáńgájíá, tó sì máa tún ayé ṣe, ìyẹn Jésù Kristi. Bíbélì sọ nípa Jésù pé:
“Ìjọba sì máa wà ní èjìká rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́ Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.”—Àìsáyà 9:6, àlàyé ìsàlẹ̀.
Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 6:10) Yàtọ̀ sí pé ó ní agbára àti ọgbọ́n tó lè fi tún ayé ṣe, kó sì bójú tó àwa tá à ń gbé inú ẹ̀, ó tún ń wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 72:12, 16) Jésù máa fi Ìjọba rẹ̀ fòpin sí gbogbo àwọn tó ń “pa ayé run,” á sì tún ayé ṣe.—Ìfihàn 11:18, àlàyé ìsàlẹ̀; Àìsáyà 35:1, 7.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí ìṣòro ojú ọjọ́ tó ń burú sí i ṣe máa yanjú, ka àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ojú Ọjọ́ Tó Ń Yí Pa Dà àti Ọjọ́ Ọ̀la Wa.”