Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Gbógun Wọ Orílẹ̀-èdè Ukraine
Láàárọ̀ kùtù February 24, 2022, àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun ja orílẹ̀-èdè Ukraine, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ kárí ayé ń sapá kí ogun má bàa wáyé. Báwo logun yìí ṣe máa kan gbogbo ayé? António Guterres tó jẹ́ akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ lọ́jọ́ mélòó kan sẹ́yìn pé: “Ìyà tó máa jẹ àwọn èèyàn àtàwọn nǹkan tó máa bà jẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Yúróòpù máa kúrò ní kèrémí, ó sì máa ṣàkóbá fún ọ̀rọ̀ ààbò kárí ayé.”
Kí ni Bíbélì sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bí irú èyí?
Jésù Kristi sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” (Mátíù 24:7) Ka àpilẹ̀kọ “Kí Ni Àmì ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn’ Tàbí ‘Àkókò Òpin’?” kó o lè rí bí Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ogun tó ń jà lónìí ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ.
Ìwé Ìfihàn nínú Bíbélì fi ẹni tó ń gun ẹṣin “aláwọ̀ iná” ṣàpèjúwe bí ogun á ṣe máa jà láyé. Ó tiẹ̀ sọ pé, ó “mú àlàáfíà kúrò ní ayé.” (Ìfihàn 6:4) Ka àpilẹ̀kọ “Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?” kó o lè mọ bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe kan ogun tó ń jà lónìí.
Ìwé Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” á máa bá ara wọn díje. (Dáníẹ́lì 11:25-45) Wo fídíò náà Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ṣẹ—Dáníẹ́lì Orí 11, kó o lè mọ ìdí tá a fi sọ pé Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ni ọba àríwá. a
Ìwé Ìfihàn tún sọ̀rọ̀ nípa “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìfihàn 16:14, 16) Àmọ́, kì í ṣe irú ogun táwọn orílẹ̀-èdè ń bá ara wọn jà lónìí ló ń sọ. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ogun tó máa jà lọ́jọ́ iwájú yìí, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?”
Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa?
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa “fòpin sí ogun kárí ayé.” (Sáàmù 46:9) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ìlérí ti Ọlọ́run ṣe nípa ọjọ́ iwájú, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa.”
Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. (Mátíù 6:9, 10) Ọ̀run ni Ìjọba náà á ti máa ṣàkóso, á sì mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ láyé. Lára ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí àlàáfíà wà kárí ayé. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àǹfààní tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún ẹ, wo fídíò Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínláàádóje (129,000) ló ń gbé ní orílẹ̀-èdè Ukraine. Bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, àwọn náà ń fara wé Jésù ní ti pé wọn ò dá sọ́rọ̀ òṣèlú, wọn ò sì lọ́wọ́ sí ogun. (Jòhánù 18:36) Kárí ayé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kéde pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa mú ogun àtàwọn ìṣòro míì tí aráyé ń dojú kọ kúrò. (Mátíù 24:14) Jọ̀wọ́ kàn sí wa tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ìlérí amọ́kànyọ̀ tó wà nínú Bíbélì.
a Tó o bá fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ka àpilẹ̀kọ “‘Ọba Àríwá’ Ní Àkókò Òpin Yìí” àti “Ta Ni ‘Ọba Àríwá’ Lónìí?”