Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Wọ́n Ṣe Ń Yìnbọn Pa Àwọn Èèyàn Nílé Ìwé?
Ní May 24, 2022, ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan wáyé nílùú Uvalde, ìpínlẹ̀ Texas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tí ìwé ìròyìn The New York Times ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó sọ pé “ọkùnrin kan yìnbọn pa ọmọléèwé mọ́kàndínlógún (19) àti olùkọ́ méjì . . . nílé ìwé kan tó ń jẹ́ Robb Elementary.”
Ó bani nínú jẹ́ pé irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìwé ìròyìn USA Today sọ pé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, “nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ (249) ìgbà ni wọ́n yìnbọn láwọn ilé ìwé lọ́dún tó kọjá, iye yẹn ló sì pọ̀ jù látọdún 1970.”
Kí nìdí táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí fi ń ṣẹlẹ̀? Kí ló lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ láìka ìwà burúkú yìí sí? Ṣé ìwà ipá tiẹ̀ lè dópin? Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
Kí nìdí tí ìwà ipá fi ń pọ̀ sí i láyé?
Bíbélì pe àkókò wa yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Ó jẹ́ ká mọ̀ pé lákòókò yìí, àwọn èèyàn máa jẹ́ ẹni tí “kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni” àti “ẹni tó burú gan-an,” wọ́n á sì máa hùwà ọ̀dájú àti ìwà ipá. Ó wá fi kún un pé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ “á máa burú sí i.” (2 Tímótì 3:1-5, 13) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Á Ṣe Máa Hùwà Lónìí?”
Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ronú pé, ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí àwọn ìwà burúkú bíi yíyìnbọn pa àwọn èèyàn nílé ìwé máa ṣẹlẹ̀?’ Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbéèrè yìí, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Nìdí Tí Nǹkan Burúkú Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Èèyàn Rere?”
Kí ló lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ láìka ìwà ipá tó kún inú ayé yìí sí?
“Nítorí gbogbo ohun tí a kọ ní ìṣáájú ni a kọ fún wa láti gba ẹ̀kọ́, kí a lè ní ìrètí . . . nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.”—Róòmù 15:4.
Àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ohun to yẹ kó o ṣe láti dáàbò bo ara ẹ nínú ayé tó kún fún ìwà ipá yìí. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka ìwé ìròyìn Jí! tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Will Violence Ever End?” lédè Gẹ̀ẹ́sì.
Tó o bá fẹ́ mọ ohun táwọn òbí lè ṣe káwọn ìròyìn tó ń bani lẹ́rù má bàa máa kó àwọn ọmọ wọn lọ́kàn sókè, ka àpilẹ̀kọ náà “Disturbing News Reports and Your Children” lédè Gẹ̀ẹ́sì.
Ṣé ìwà ipá yìí tiẹ̀ lè dópin?
“Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”—Sáàmù 72:14.
“Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀, wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn. Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Míkà 4:3.
Ọlọ́run máa ṣe ohun tí èèyàn èyíkéyìí ò lè ṣe. Ìjọba ẹ̀ máa pa gbogbo ohun ìjà run, á sì fòpin sí ìwà ipá pátápátá. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe, ka àpilẹ̀kọ náà “Àlàáfíà Máa Pọ̀ Yanturu Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.”