Bó O Ṣe Lè Borí Àníyàn
Tí àníyàn bá ti pọ̀ jù, ó lè ṣe àkóbá fún ìlera rẹ, ó sì lè fa ìdààmú ọkàn. Kódà, ó tún lè dá ìṣòro mìíràn sílẹ̀, tó máa le ju ìṣòro àkọ́kọ́ tó fa ìrònú fún ẹ.
Àwọn àbá tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣàníyàn jù
Má ṣe máa fetí sí ìròyìn burúkú ní gbogbo ìgbà. O ò nílò láti mọ gbogbo ìsọfúnni nípa àwọn wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀. Tí o bá ń fetí sí ìròyìn burúkú ní gbogbo ìgbà, ó lè mú kí ẹ̀rù máa bà ọ́, kó o sì sọ ìrètí nù.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ̀mí tí ìdààmú bá máa ń tánni lókun.”—Òwe 17:22.
“Ó rọrùn láti sọ gbígbọ́ àwọn ìròyìn tuntun dàṣà, àmọ́ kì í ṣe àṣà tó dáa. Tí mo bá dín ìròyìn tí mò ń gbọ́ kù, àníyàn mi náà máa ń dín kù.”—John.
Ronú nípa rẹ̀: Ṣé dandan ni kó o gbọ́ gbogbo ìròyìn tuntun?
Ṣètò àsìkò rẹ, kí o sì tẹ̀ lé e. Gbìyànjú láti ní àsìkò kan pàtó tí wàá máa jí, jẹun, ṣe iṣẹ́ ilé, tí wàá sì máa sùn. Tó o bá ní ètò fún àwọn ohun tó ò ń ṣe, ó máa mú kí ìgbé ayé rẹ wà létòlétò, èyí sì máa dín àníyàn rẹ kù.
Ìlànà Bíbélì: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.”—Òwe 21:5.
“Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 bẹ̀rẹ̀, mi ò tẹ̀ lé ètò tí mo ṣe mọ́, èyí wá mú kí n máa lo àsìkò tó pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ nídìí eré ìnàjú. Mo fẹ́ lo àsìkò mi lọ́nà tó dáa, nítorí èyí, mo ṣètò bí màá ṣe máa ṣe àwọn ojúṣe mi ojoojúmọ́.”—Joseph.
Ronú nípa rẹ̀: Ṣé o ti ṣètò àsìkò rẹ lọ́nà tó máa mú kó o lè ṣe àwọn nǹkan pàtàkì ní ojoojúmọ́?
Ní èrò rere. Tó o bá ń ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan tí ò tíì ṣẹlẹ̀ tàbí nǹkan burúkú tó lè ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú, ọkàn rẹ ò ní balẹ̀. O ò ṣe ronú nípa nǹkan méjì sí mẹ́ta tó o lè dúpẹ́ fún?
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa dúpẹ́.”—Kólósè 3:15.
“Kíka Bíbélì máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti yẹra fún ìròyìn búburú, ó sì máa ń jẹ́ kí n máa ronú ohun rere. Ó lè dà bí ohun tí ò tó nǹkan, àmọ́ ó máa ń wúlò gan-an!”—Lisa.
Ronú nípa rẹ̀: Ṣé o sábà máa ń darí gbogbo àfiyèsí rẹ sórí àwọn nǹkan tí kò dáa tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ, tí wàá sì gbàgbé àwọn nǹkan dáadáa?
Ronú nípa àwọn ẹlòmíì. Tí àníyàn bá ti gbà ẹ́ lọ́kàn, o lè fẹ́ dá wà, dípò kó o jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ronú nípa bó o ṣe lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.
Ìlànà Bíbélì: “Bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.”—Fílípì 2:4.
“Inú mi máa ń dùn tí mo bá ṣe nǹkan dáadáa fún àwọn ẹlòmíì. Tí mo bá ń ṣe àwọn nǹkan tó máa mú inú àwọn ẹlòmíì dùn, àníyàn tèmi náà máa ń dín kù. Kódà, mi ò tiẹ̀ ní ráyè ṣàníyàn mọ́.”—Maria.
Ronú nípa rẹ̀: Ṣé o mọ àwọn èèyàn tí wọ́n lè nílò àfikún ìrànlọ́wọ́, ọ̀nà wo lo lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́?
Ní ìlera tó dáa. Máa ṣe eré ìmárale tí ó tó, kí o sì máa sinmi. Jẹ oúnjẹ aṣaralóore. Tí o bá ń bójú tó ìlera rẹ, o ò ní máa fìgbà gbogbo ronú lórí àwọn ìṣòro, wàá sì gbà pé nǹkan ṣì máa dáa.
Ìlànà Bíbélì: “Àǹfààní . . . wà nínú eré ìmárale.”—1 Tímótì 4:8.
“Èmi àti ọmọ mi ò lè rìn síbí rìn sọ́hùn-ún bí a ṣe fẹ́ níta. Nítorí èyí, a ṣètò láti máa ṣe eré ìmárale nínú ilé wa. Èyí mú kí inú wa dùn sí i, àjọṣe wa sì ti dára sí i.”—Catherine.
Ronú nípa rẹ̀: Ǹjẹ́ o nílò láti jẹ oúnjẹ aṣaralóore sí i, kí o sì túbọ̀ máa ṣe eré ìmárale, kí ìlera rẹ lè sunwọ̀n sí i?
Ní àfikún sí fífi àwọn àbá yìí sílò, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ti jàǹfààní nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlérí tó ṣeé gbára lé tó wà nínú Bíbélì nípa ọjọ́ ọ̀la tó dára. Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?”