Ṣé Nǹkan Ṣì Lè Pa Dà sí Bó Ṣe Wà Tẹ́lẹ̀ Ṣáájú Àrùn Corona? Bí Bíbélì Ṣe Lè Ràn Wá Lọ́wọ́
Olórí ìjọba ilẹ̀ Jámánì tó ń jẹ́ Angela Merkel sọ pé “Gbogbo wa la fẹ́ kí nǹkan pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.”
Àrùn Corona ti ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé, torí náà ó ṣeé ṣe kó o gbà pẹ̀lú ohun tó sọ. Àmọ́ kí ló túmọ̀ sí pé kí nǹkan pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀? Kí ló sì wu àwọn èèyàn láti máa ṣe?
Wọ́n fẹ́ máa ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ó wu àwọn kan pé kí wọ́n láǹfààní láti sún mọ́ àwọn èèyàn wọn, kí wọ́n dì mọ́ra, kí wọ́n bọ ara wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì rin ìrìn àjò. Bí Dókítà Anthony Fauci a ṣe sọ, “Kí nǹkan tó lè pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ó gba pé kéèyàn lè lọ sílé oúnjẹ, kéèyàn lè lọ sílé sinimá tàbí kéèyàn lè ṣe nǹkan míì tó jọ bẹ́ẹ̀.”
Wọ́n fẹ́ mú kí bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan dáa sí i. Ọ̀pọ̀ lo àǹfààní yìí láti ṣàtúnṣe sí bí wọ́n ṣe ń gbé ayé wọn, kó lè dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀ gbà pé àwọn nǹkan kan gbọ́dọ̀ yí pa dà, irú bí iṣẹ́ tó ń tánni lókun tó sì ń gba ọ̀pọ̀ àkókò, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti báwọn èèyàn ṣe ń ní ìdààmú ọkàn. Ọ̀gbẹ́ni Klaus Schwab tó jẹ́ olùdásílẹ̀ Àpérò Lórí Ètò Ọrọ̀ Ajé Àgbáyé sọ pé: “Àjàkálẹ̀ àrùn yìí fún wa ní àǹfààní kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ti pé ó jẹ́ ká lè ronú nípa ìgbésí ayé wa, àti bá a ṣe fẹ́ kí ayé wa yìí rí, ó sì fún wa láǹfààní láti yí ayé yìí pa dà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àǹfààní yìí ò lè wà pẹ́ títí.”
Àwọn kan gbà pé àjàkálẹ̀ àrùn yìí ti fa ọ̀pọ̀ ìṣòro débi tí wọ́n fi ronú pé kò sí bí nǹkan ṣe lè pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ti pàdánù iṣẹ́ wọn, ilé wọn àti ìlera wọn, èyí tó burú jù ni pé lára àwọn èèyàn wọn ti kú.
Òótọ́ ni pé kò sẹ́ni tó lè mọ bí ayé yìí ṣe máa rí lẹ́yìn tí àjàkálẹ̀ àrùn yìí bá dópin. (Oníwàásù 9:11) Àmọ́, Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi ojú tó tọ́ wo ọjọ́ iwájú, ká sì lè fara da ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la kan tó lè yà wá lẹ́nu àmọ́ tó ṣeé gbára lé.
Bó o ṣe lè fojú tó tọ́ wo àrùn Corona
Ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé onírúurú àìsàn tàbí “àjàkálẹ̀ àrùn” máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Lúùkù 21:11; Mátíù 24:3) Tá a bá ń ronú lórí ẹsẹ Bíbélì yìí, ìyẹn á jẹ́ ká rí i pé àrùn Corona wà lára àwọn nǹkan bí ogun, ìmìtìtì ilẹ̀ àti àìtó oúnjẹ tí Bíbélì sọ pé á máa ṣẹlẹ̀.
Bí ohun tá a mọ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ṣì lè dáa sí i lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn yìí, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ‘àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ là ń gbé yìí. (2 Tímótì 3:1) Ohun tá a mọ̀ yìí máa jẹ́ ká lè fi ojú tó tọ́ wo bí nǹkan ṣe rí lásìkò tí nǹkan nira yìí.
Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé àyípadà ńlá máa tó bá ayé yìí níbi tá a ti ń dojú kọ onírúurú ìṣòro. Àyípadà wo nìyẹn?
Kò ní sí àjàkálẹ̀ àrùn mọ́ lọ́jọ́ iwájú
Kì í ṣe àwọn ìṣòro tó nira tá à ń kojú báyìí nìkan ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀, ó tún ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí nǹkan máa dáa. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn àyípadà kan tí ìjọba èèyàn ò lè ṣe àfi Ọlọ́run nìkan. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé Ọlọ́run “máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìfihàn 21:4.
Jèhófà b Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” (Ìfihàn 21:5) Ó máa yanjú àwọn ìṣòro tó wà láyé yìí títí kan àjàkálẹ̀ àrùn tó ń mú kí nǹkan túbọ̀ nira. Ó máa ṣe àwọn nǹkan yìí:
Ìlera pípé, kò sì ní sí àìsàn àti ikú mọ́.—Àìsáyà 25:8; 33:24.
Iṣẹ́ tó ń tẹ́ni lọ́rùn tó sì tún ń fini lọ́kàn balẹ̀, kì í ṣe iṣẹ́ tó ń gba àkókò ẹni tó sì ń tánni lókun.—Àìsáyà 65:22, 23.
Ó máa fòpin sí ipò òṣì àti ebi.—Sáàmù 72:12, 13; 145:16.
A máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀dùn ọkàn tá a ní nítorí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa, a sì máa rí àwọn èèyàn wa tó ti kú.—Àìsáyà 65:17; Ìṣe 24:15.
Bí ohun tá a mọ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́: Bíbélì sọ pé: “A ní ìrètí yìí bí ìdákọ̀ró fún ẹ̀mí wa.” (Hébérù 6:19, àlàyé ìsàlẹ̀) Ìrètí yìí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa máa jẹ́ ká lè fara da ohun yòówù ká máa kojú lónìí. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ká sì láyọ̀.
Àmọ́ ṣé a lè gba àwọn ìlérí Bíbélì yìí gbọ́? Wo àpilẹ̀kọ náà, “Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì, Ó sì Ṣeé Gbára Lé.”
Àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́yìn àjàkálẹ̀ àrùn yìí
Jẹ́ kí ẹ̀mí jọ ẹ́ lójú
Bíbélì: “Ọgbọ́n máa ń dá ẹ̀mí àwọn tó ní in sí.”—Oníwàásù 7:12.
Bí ohun tá a mọ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́: Ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu kó o má bàa kó àrùn. Fara balẹ̀ kíyè sí bí nǹkan ṣe ń lọ ládùúgbò ẹ. Bí àpẹẹrẹ, òfin tó de ọ̀rọ̀ ààbò àti ìlera, báwọn èèyàn ṣe ń kó àjàkálẹ̀ àrùn àti iye èèyàn tó ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára wọn pé.
Máa kíyè sára
Bíbélì: “Ọlọ́gbọ́n máa ń ṣọ́ra, ó sì ń yẹra fún ìwà burúkú, àmọ́ òmùgọ̀ kì í kíyè sára, ó sì máa ń dá ara rẹ̀ lójú jù.”—Òwe 14:16.
Bí ohun tá a mọ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́: Máa ṣe àwọn nǹkan tó yẹ kí ìlera rẹ lè dáa sí i. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé ó ṣeé ṣe kí àrùn Corona pẹ́ kó tó lọ.
Máa gba àwọn ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé
Bíbélì: “Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.”—Òwe 14:15.
Bí ohun tá a mọ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́: Fara balẹ̀ ronú nípa ìmọ̀ràn tó o máa tẹ̀ lé. Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìsọfúnni yálà ó jóòótọ́ tàbí kò jóòótọ́ lò ń tẹ̀ lé, ó lè ṣàkóbá fún ìlera ẹ.
Ní èrò tó tọ́
Bíbélì: “Má sọ pé, ‘Kí nìdí tí àwọn ọjọ́ àtijọ́ fi sàn ju ti ìgbà yìí lọ?’ torí pé kì í ṣe ọgbọ́n ló mú kí o béèrè bẹ́ẹ̀.”—Oníwàásù 7:10.
Bí ohun tá a mọ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́: Pinnu pé wà á gbé ìgbé ayé tó dáa láìka ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Kò yẹ kó o máa ronú pé nǹkan dáa ju báyìí lọ ṣáájú àkókó àjàkálẹ̀ àrùn yìí, kò sì yẹ kó o máa ronú nípa àwọn nǹkan tí o ò lè ṣe torí àjàkálẹ̀ àrùn náà.
Bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíì
Bíbélì: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú èèyàn.”—1 Pétérù 2:17.
Bí ohun tá a mọ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́: Èrò àwọn èèyàn nípa àrùn Corona àti ìpalára tó ń fà yàtọ̀ síra. Má ṣe ta ko èrò ẹnikẹ́ni, àmọ́ dúró lórí ìpinnu tó dáa tó o ti ṣe. Máa gba ti àwọn tí ò tíì gba abẹ́rẹ́ àjẹsára rò, títí kan àwọn àgbàlagbà àtàwọn tí wọ́n ní àìsàn tí wọ́n ń bá yí.
Máa ṣe sùúrù
Bíbélì: “Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù àti inú rere.”—1 Kọ́ríńtì 13:4.
Bí ohun tá a mọ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́: Máa ṣe sùúrù pẹ̀lú àwọn èèyàn, tí ẹ̀rù bá ń bà wọ́n láti máa ṣe àwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe kí àjàkálẹ̀ àrùn náà tó bẹ̀rẹ̀. Kí ìwọ náà máa ṣe sùúrù tó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tó o máa ń ṣe kí àjàkálẹ̀ àrùn náà tó bẹ̀rẹ̀.
Bí Bíbélì ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti fara da àjàkálẹ̀ àrùn náà
Ọkàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà balẹ̀ torí Bíbélì ṣèlérí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn kì í sì jẹ́ ká máa káyà sókè torí àjàkálẹ̀ àrùn yìí. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń pa àṣẹ Bíbélì mọ́ pé ká máa péjọ láti jọ́sìn Ọlọ́run, ìyẹn sì máa ń fún wa níṣìírí. (Hébérù 10:24, 25) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣèpàdé wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì torí àrun Corona, gbogbo èèyàn la sì máa ń pè.
Àwọn kan gbà pé bí àwọn ṣe ń dara pọ̀ mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípàdé wa ti ràn àwọn lọ́wọ́ gan-an lásìkò tí nǹkan nira yìí. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ní àrun Corona dara pọ̀ mọ́ ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìsàn náà ń dà á láàmú gan-an, àwọn ìpàdé náà fún-un lókun. Ó wá sọ pé: “Ṣe ló ń ṣe mí bíi pé mo wà láàárín àwọn ọmọ ìyá mi. Bí mo ṣe ń ka Bíbélì ń fi mí lọ́kàn balẹ̀, ó sì ń jẹ́ kára tù mí. Ó tún máa ń jẹ́ kí n gbọ́kàn kúrò lórí ìṣòro mi, kí n sì máa fojú sọ́nà sígbà tí àwọn ìṣòro yẹn ò ní sí mọ́. Ọjọ́ pẹ́ tó ti ń wù mí láti sún mọ́ Ọlọ́run, ẹ ṣeun gan-an tẹ́ ẹ ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.”
a Alábòójútó Àjọ Tó Ń Rí sí Èèwọ̀ Ara Àtàwọn Àrùn Tó Ń Ràn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
b Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà lórúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.