Àkọsílẹ̀ Ayé Àtijọ́ Kan Jẹ́rìí Sí Ibi Tí Ẹ̀yà Ísírẹ́lì Kan Ti Wà
Bíbélì sọ pé nígbà kan, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn tó wà ní Ilẹ̀ Ìlérí, tí wọ́n sì pín ilẹ̀ náà láàárín àwọn ẹ̀yà wọn, ìdílé mẹ́wàá lára ẹ̀yà Mánásè ló gba àgbègbè ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì, wọ́n sì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹ̀yà tó kù. (Jóṣúà 17:1-6) Ǹjẹ́ àwọn awalẹ̀pìtàn rí ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ ni?
Lọ́dún 1910, wọ́n wú àwọn àpáàdì kan tí wọ́n kọ nǹkan sí lára jáde ní Samáríà. Èdè Hébérù ni wọ́n fi kọ nǹkan sára àwọn àpáàdì yìí, ó ní àwọn àkọsílẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn ohun mèremère bí, òróró àti wáìnì wá sí ààfin ọba olú ìlú ńlá náà. Ọgọ́rùn-ún kan ó lé méjì [102] àwọn àpáàdì ni wọ́n rí, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ Ṣáájú Sànmánì Kristẹni làwọn àpáàdì náà ti wà, àmọ́ kìkì mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] lára wọn lèèyàn lè rí nǹkan tí wọ́n kọ sára wọn kà. Lápapọ̀, ọjọ́, orúkọ agbo ìdílé, orúkọ àwọn tó fi ọjà náà ránṣẹ́ àti orúkọ àwọn tó fẹ́ gba ọjà náà wà lára àwọn àpáàdì náà.
Ó hàn gbangba pé gbogbo ìdílé tí wọ́n dárúkọ nínú àpáàdì náà jẹ́ ti ẹ̀yà ìdílé Mánásè. Bí ìwé NIV Archaeological Study Bible ṣe sọ, ńṣe lèyí “jẹ́ ká rí i pé yàtọ̀ sínú Bíbélì ibòmíì rèé tí wọ́n ti dárúkọ àwọn agbo ìdílé Mánásè àti àgbègbè tí Bíbélì sọ pé wọ́n tẹ̀ dó sí.”
Àwọn àpáàdì tí wọ́n hú jáde nílùú Samáríà tún jẹ́rìí sí i pé òótọ́ lohun tí òǹkọ̀wé Bíbélì tó ń jẹ́ Émọ́sì sọ, ẹni tó sọ nípa àwọn olówó ayé ìgbà yẹn pé: “Wọ́n ń fi abọ́ mu wáìnì wọ́n sì ń fi òróró tó dára jù lọ para.” (Émọ́sì 6:1, 6) Àwọn àpáàdì tí wọ́n hú nílùú Samáríà tún jẹ́rìí sí i pé irú àwọn ẹrù bẹ́ẹ̀ wà lára àwọn ẹrù tí wọ́n máa ń kó wá sí apá ilẹ̀ ibi tí àwọn ìdílé mẹ́wàá lára ẹ̀yà Mánásè tẹ̀ dó sí.