ORÍ 6
“Ó Kọ́ Ìgbọràn”
1, 2. Kí ló múnú bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ dùn bó ṣe rí i tí ọmọ náà gbọ́ràn sí i lẹ́nu, báwo lèyí sì ṣe jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jèhófà?
BÀBÁ kan ń wo ọmọ rẹ̀ látojú fèrèsé bóun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe ń gbá bọ́ọ̀lù. Bọ́ún ni bọ́ọ̀lù ọ̀hún ta kúrò níbi tí wọ́n ti ń gbá a, ó di kọ́ṣọ́ lódìkejì títì. Ọmọ náà fojú sin bọ́ọ̀lù yẹn lọ bíi pé kó sáré lọ mú un. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ rọ̀ ọ́ pé kó lọ mú un wá, ṣùgbọ́n ńṣe lọmọ náà mi orí. Ó ní: “Wọ́n ti ní mi ò gbọ́dọ̀ fo títì.” Inú bàbá yẹn dùn, ó rẹ́rìn-ín músẹ́.
2 Kí ló jẹ́ kí inú bàbá yẹn dùn? Ohun tó múnú ẹ̀ dùn ni pé ó ti kìlọ̀ fọ́mọ ẹ̀ tẹ́lẹ̀ pé kò gbọ́dọ̀ dá fo títì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ yẹn ò mọ̀ pé bàbá ń wo òun, nígbà tó ṣègbọràn yẹn, bàbá rẹ̀ mọ̀ pé ọmọ òun ń gbọ́rọ̀ sóun lẹ́nu àti pé kò ní kó sí ìṣòro. Bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Bàbá wa ọ̀run Jèhófà lọ̀rọ̀ ọmọ tá a sọ yẹn ṣe rí lára bàbá rẹ̀. Ọlọ́run mọ̀ pé bá a bá máa jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ tá a sì máa wà láàyè láti rí bí ọjọ́ ọ̀la tó ti ṣètò sílẹ̀ ní sẹpẹ́ ṣe máa jẹ́ àgbàyanu tó, a gbọ́dọ̀ kọ́ láti gbọ́kàn lé òun ká sì máa gbọ́rọ̀ sí òun lẹ́nu. (Òwe 3:5, 6) Kíyẹn bàa lè ṣeé ṣe ló ṣe rán olùkọ́ tó ju olùkọ́ lọ sí wa.
3, 4. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà “kọ́ ìgbọràn,” báwo ló sì ṣe jẹ́ ẹni tá a sọ “di pípé”? Ṣàpèjúwe rẹ̀.
3 Bíbélì sọ ohun àgbàyanu kan nípa Jésù pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ Ọmọ, ó kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀; àti lẹ́yìn tí a ti sọ ọ́ di pípé, ó di ẹni tí ó ní ẹrù iṣẹ́ fún mímú ìgbàlà àìnípẹ̀kun wá fún gbogbo àwọn tí ń ṣègbọràn sí i.” (Hébérù 5:8, 9) Ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún lọmọ yìí ti fi wà lọ́run. Ìṣojú rẹ̀ ni Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ tó kó sòdí ṣe ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àkọ́bí Ọmọ yìí ò bá wọn lọ́wọ́ sí i. Ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí sọ nípa rẹ̀ ni pé: ‘Èmi kò ya ọlọ̀tẹ̀.’ (Aísáyà ) Bó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, báwo ni ọ̀rọ̀ pé “ó kọ́ ìgbọràn” ṣe lè wá kan Ọmọ onígbọràn tó jẹ́ ẹni pípé yìí? Ọ̀nà wo nirú ẹ̀dá pípé bẹ́ẹ̀ ṣe lè tún jẹ́ ẹni tí a sọ “di pípé”? 50:5
4 Wo àpèjúwe yìí ná. Sójà kan báyìí wà tó ní idà onírin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ò tíì lo idà náà wò rí lójú ogun láti mọ bó ṣe lágbára tó, wọ́n rọ idà náà dáadáa, ó sì gún régé. Àmọ́, sójà yìí fi idà ọ̀hún gba pààrọ̀ èyí tí wọ́n fi irin tó lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ ṣe. Wọ́n ti lo idà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà yìí dáadáa lójú ogun. Pàṣípààrọ̀ tó dáa ló ṣe, àbí? Bákan náà, kí Jésù tó wá sáyé, ó ti fi hàn pé òun jẹ́ onígbọràn láìkù síbì kan. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó kúrò láyé, ìgbọràn rẹ̀ ti wá di àkọ̀tun látòkèdélẹ̀. Àwọn ìdánwò tó kojú láyé, tí ì bá má kojú lọ́run, ló dán ìgbọràn rẹ̀ wò tó fi túbọ̀ lágbára bẹ́ẹ̀.
5. Kí ló jẹ́ kí ìgbọràn Jésù ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀, kí la sì máa jíròrò ní orí yìí?
5 Ìgbọràn wà lára nǹkan pàtàkì tó mú kí Jésù wá sáyé. Gẹ́gẹ́ bí “Ádámù ìkẹyìn,” ó wá ṣe ohun táwọn òbí wa àkọ́kọ́ ò lè ṣe, ìyẹn ni ṣíṣègbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà kódà lójú àdánwò. (1 Kọ́ríńtì 15:45) Síbẹ̀, ìgbọràn Jésù kì í ṣe àfaraṣe-má-fọkàn-ṣe o. Gbogbo ọkàn ni Jésù fi ṣègbọràn. Ó sì ṣe é tayọ̀tayọ̀. Ṣíṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ ṣe pàtàkì sí i ju jíjẹun lọ! (Jòhánù 4:34) Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onígbọràn bíi ti Jésù? Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ohun tó máa ń mú kí Jésù ṣègbọràn ná. Bá a bá wo ohun tó mú kí Jésù ṣègbọràn, á jẹ́ káwa náà máa ṣègbọràn, á jẹ́ ká lè máa yẹra fáwọn nǹkan tó lè dán wa wò, á sì jẹ́ ká lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, la óò wá ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àǹfààní mélòó kan tó ń wá látinú jíjẹ́ onígbọràn bíi Kristi.
Ohun Tó Ń Mú Kí Jésù Máa Ṣègbọràn
6, 7. Kí ni díẹ̀ lára ohun tó máa ń mú kí Jésù ṣègbọràn?
6 Ohun tó wà nínú ọkàn Jésù ló mú kó máa ṣègbọràn. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ní Orí 3 ìwé yìí, onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni Jésù. Ìgbéraga ni kì í jẹ́ káwọn èèyàn lè ṣègbọràn, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ńṣe ni ìrẹ̀lẹ̀ máa ń mú kéèyàn lè ṣègbọràn sí Jèhófà tinútinú. (Ẹ́kísódù 5:1, 2; 1 Pétérù 5:5, 6) Ohun tí Jésù nífẹ̀ẹ́ sí àtohun tó kórìíra tún wà lára ohun tó máa ń mú kó ṣègbọràn.
7 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jésù nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Bàbá rẹ̀ ọ̀run. A óò jíròrò ìfẹ́ yìí lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ ní Orí 13. Irú ìfẹ́ yẹn ló jẹ́ kí Jésù bẹ̀rù Ọlọ́run. Nítorí bí ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà ṣe lágbára tó àti bí ọ̀wọ̀ tó ní fún un ṣe jinlẹ̀ tó, ó máa ń bẹ̀rù láti ṣe ohun tí Bàbá rẹ̀ ò fẹ́. Torí pé Jésù ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni Jèhófà ṣe máa ń fi inú dídùn dáhùn àdúrà rẹ̀. (Hébérù 5:7) Bákan náà, ìbẹ̀rù Jèhófà lohun pàtàkì tó mú kí Jèhófà yan Jésù láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba.—Aísáyà 11:3.
8, 9. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀, báwo ni ìwà òdodo àti ìwà burúkú ṣe máa ń rí lára Jésù, ọ̀nà wo ló sì gbà fi bó ṣe rí lára rẹ̀ hán?
8 Bákan náà, ẹní bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ kórìíra ohun tí Jèhófà kórìíra. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ yìí tí Bíbélì darí sí Mèsáyà Ọba: “Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà burúkú. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ ńláǹlà yàn ọ́ ju àwọn alájọṣe rẹ.” (Sáàmù 45:7) Àwọn “alájọṣe” Jésù làwọn ọba yòókù tó jẹ látinú ìdílé Dáfídì Ọba. Ju ẹnikẹ́ni lára wọn lọ, ìdí wà fún Jésù láti fò fáyọ̀, àní kí ayọ̀ rẹ̀ kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún yíyàn tí Ọlọ́run fòróró yàn án. Kí nìdí? Ìdí ni pé àǹfààní tí Ọlọ́run fi san án lẹ́san kò ṣeé fi wé ti àwọn ọba yòókù, ìjọba rẹ̀ sì máa ṣe aráàlú láǹfààní ju tiwọn lọ. Ohun tó sì mú kí Ọlọ́run san án láwọn ẹ̀san wọ̀nyẹn ni pé ó ṣègbọràn sí Ọlọ́run nínú ohun gbogbo nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ òdodo ó sì kórìíra ìwà burúkú.
9 Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ bí òdodo àti ìwà burúkú ṣe máa ń rí lára òun? Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó fún wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n sì ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ yẹn, báwo ló ṣe rí lára rẹ̀? Inú rẹ̀ dùn jọjọ. (Lúùkù 10:1, 17, 21) Bákan náà, nígbà táwọn ará Jerúsálẹ́mù ò jáwọ́ nínú ìwà àìgbọràn tí wọ́n ń hù, tí wọ́n sì kọ̀ tí wọn ò kọbi ara sí gbogbo ìsapá Jésù láti ràn wọ́n lọ́wọ́, báwo ló ṣe rí lára Jésù? Ó sunkún nítorí pé àwọn aráàlú náà ya ọlọ̀tẹ̀. (Lúùkù 19:41, 42) Jésù máa ń mọ ohun táwọn èèyàn bá ṣe lára, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú.
10. Báwo ló ṣe yẹ kí híhùwà òdodo tàbí híhùwà búburú máa rí lára wa, kí ló sì lè mú kó máa rí bẹ́ẹ̀ lára wa?
10 Bá a bá ṣàṣàrò nípa bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jésù, á jẹ́ káwa náà lè ṣàyẹ̀wò ohun tó ń mú wa ṣègbọràn sí Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, a ṣì lè jẹ́ kí ìfẹ́ ohun rere jinlẹ̀ lọ́kàn wa, ká sì fi gbogbo ọkàn wa kórìíra ìwà búburú. Ó ṣe pàtàkì ká gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti lè máa ní irú èrò tí Òun àti Ọmọ rẹ̀ ní. (Sáàmù 51:10) Síbẹ̀ a ní láti yẹra fún àwọn nǹkan tó lè gbà wá lọ́kàn tí ò ní jẹ́ ká máa ní irú èrò bẹ́ẹ̀. A ní láti ṣọ́ra gan-an tó bá dọ̀rọ̀ irú eré ìnàjú tá a máa ṣe àtàwọn tá a máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́. (Òwe 13:20; Fílípì 4:8) Bó bá jẹ́ pé ohun tó mú kí Jésù ṣègbọràn ló ń mú àwa náà ṣègbọràn, ìgbọràn wa á lè jẹ́ tinútinú. Ohun rere la óò máa ṣe nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe é. Kíkọ̀ tá a bá kọ̀ láti hùwà tí kò dáa kò ní jẹ́ pé torí kí àṣírí wa má bàa tú, kàkà bẹ́ẹ̀, á jẹ́ torí pé á kórìíra irú ìwà bẹ́ẹ̀.
“Kò Dá Ẹ̀ṣẹ̀ Kankan”
11, 12. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jésù níbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? (b) Báwo ni Sátánì ṣe kọ́kọ́ dán Jésù wò, ètekéte wo ló sì pa?
11 Jésù kojú àdánwò kan tó dán bó ṣe kórìíra ẹ̀ṣẹ̀ tó wò níbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó lo ogójì ọ̀sán àti ogójì òru nínú aginjù láìfẹnu kan oúnjẹ. Lẹ́yìn tí ogójì ọjọ́ pé, Sátánì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti lè dán an wò. Ẹ wá wo bí ètekéte Èṣù ṣe pọ̀ tó o.—Mátíù 4:1-11.
12 Ohun tó kọ́kọ́ sọ ni pé: “Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún àwọn òkúta wọ̀nyí pé kí wọ́n di àwọn ìṣù búrẹ́dì.” (Mátíù 4:3) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí Jésù lásìkò yẹn lẹ́yìn ààwẹ̀ ọlọ́jọ́ gbọọrọ tó ti gbà? Bíbélì sojú abẹ níkòó pé: “Ebi wá ń pa á.” (Mátíù 4:2) Nítorí náà, Sátánì lo àǹfààní ti ebi táá ti máa pa Jésù, kò sì sí iyè méjì pé ńṣe ló dìídì dúró dìgbà tí àárẹ̀ ti mú Jésù. Tún kíyè sí ọ̀rọ̀ tí Sátánì fi dẹ Jésù wò, ó ní: “Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.” Sátánì kúkú mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá” ni Jésù. (Kólósè 1:15) Jésù, ní tiẹ̀ ò gbà kí Sátánì ti òun débi tóun á fi ṣàìgbọràn. Jésù mọ̀ pé kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pé kóun máa fi agbára òun ṣe ohun tó bá wu òun. Ó kọ̀ láti ṣe ohun tí Èṣù ní kó ṣe, ó fi hàn pé tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ lòun fi gbọ́kàn lé Jèhófà láti pèsè fóun àti láti tọ́ òun sọ́nà.—Mátíù 4:4.
13-15. (a) Kí ni àdánwò kejì àti ẹ̀kẹta tí Sátánì gbé síwájú Jésù, kí sì lèsì Jésù? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé kò sígbà kan tí Jésù kì í wà lójúfò torí Sátánì?
13 Nígbà tí Sátánì máa dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kejì, ibi tó ga fíofío lórí òrùlé tẹ́ńpìlì ló mú un lọ. Ó wá fọgbọ́n ẹ̀tàn yí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti lè mú kí Jésù ṣe àṣehàn ara rẹ̀ nípa bíbẹ́ sílẹ̀ látorí òkè gíga yẹn, pé àwọn áńgẹ́lì kò ní jẹ́ kó fara pa. Báwọn ogunlọ́gọ̀ tó wà ní tẹ́ńpìlì bá rí Jésù pẹ̀lú irú iṣẹ́ ìyanu yẹn, ǹjẹ́ a máa lè rẹ́ni táá tún jiyàn rẹ̀ pé òun kọ́ ni Mèsáyà? Bó bá sì wá jẹ́ pé nítorí pé Jésù ń ṣe àṣehàn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn ṣe gbà pé òun ni Mèsáyà, ṣé kì í ṣe pé ńṣe ni Jésù ń sá fún ọ̀pọ̀ ìnira àti ìṣòro tó yẹ kó kojú? Àfàìmọ̀. Ṣùgbọ́n Jésù mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí Mèsáyà fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe iṣẹ́ rẹ̀, kì í ṣe pé kó wá mú káwọn èèyàn gbà á gbọ́ nítorí àṣehàn. (Aísáyà 42:1, 2) Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù ò gbà kí Sátánì mú òun ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Kò jẹ́ kí ìfẹ́ àtidi olókìkí dẹkùn mú òun.
14 Ìfẹ́ láti dẹni tó ní àṣẹ níkàáwọ́ ńkọ́? Nínú àdánwò kẹta, Sátánì sọ pé bí Jésù bá lè jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, gbogbo ìjọba ayé lòun á gbé lé e lọ́wọ́. Ǹjẹ́ Jésù ro ohun tí Sátánì fi lọ̀ ọ́ lẹ́ẹ̀mejì? Èsì Jésù ni pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’” (Mátíù 4:10) Kò sí nǹkan náà tó lè mú kí Jésù jọ́sìn ọlọ́run mìíràn. Kò sí àṣẹ tàbí òkìkí tẹ́nì kan lè fi lọ Jésù tó lè mú kó ṣàìgbọràn kankan.
15 Ǹjẹ́ Sátánì fi Jésù lọ́rùn sílẹ̀? Ó kúkú lọ lẹ́yìn tí Jésù pàṣẹ fún un yẹn. Síbẹ̀ Ìhìn Rere Lúùkù sọ pé Èṣù “fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ títí di àkókò mìíràn tí ó wọ̀” ni (Lúùkù 4:13) Ó dájú pé Sátánì ò ní ṣàìwá àkókò mìíràn láti dán Jésù wò, àfi tí kò bá sí láyé mọ́ ló kù. Bíbélì sọ fún wa pé Jésù dojú kọ àdánwò “ní gbogbo ọ̀nà.” (Hébérù 4:15) Nítorí náà, kò sígbà kankan tí Jésù kì í wà lójúfò, ńṣe làwa náà sì gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò.
16. Ọ̀nà wo ni Sátánì gbà ń dán àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wò lónìí, báwo la sì ṣe lè rí i pé kò rí wa gbé ṣe?
16 Títí dòní, Sátánì ṣì ń dán àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wò. Ó bani nínú jẹ́ pé wẹ́rẹ́ báyìí lọwọ́ rẹ̀ máa ń tó wa lọ́pọ̀ ìgbà, nítorí jíjẹ́ tá a jẹ́ aláìpé. Nǹkan tí Sátánì sábà máa ń fọgbọ́n ẹ̀tàn rẹ̀ lò ni ìmọtara-ẹni-nìkan, ìgbéraga àti ìfẹ́ láti ní àṣẹ níkàáwọ́. Ó lè lo ìfẹ́ ọrọ̀ láti sọ wá dẹni tó ń lé àwọn nǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí! Ó ṣe pàtàkì pé ká máa fara balẹ̀ ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti yẹ ara wa wò. Ó yẹ ká máa ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Jòhánù 2:15-17. Bá a ṣe ń ṣàṣàrò náà, a lè máa bi ara wa bóyá ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara inú ètò àwọn nǹkan yìí, lílépa àtikó dúkìá jọ àti ìfẹ́ láti máa ṣe fọ́rífọ́rí fáwọn ẹlòmíì ti gbà wá lọ́kàn débi tí a ò fi ní rántí ìfẹ́ tá a ní fún Bàbá wa ọ̀run mọ́. Ó pọn dandan ká máa rántí pé, ayé yìí ń ré kọjá lọ tòun ti Sátánì olùṣàkóso rẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbà fún un láti fi ètekéte rẹ̀ tàn wá dẹ́ṣẹ̀! Ọ̀gá wa ni kẹ́ ẹ jẹ́ ká máa fìwà jọ, torí pé “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.”—1 Pétérù 2:22.
“Nígbà Gbogbo Ni Mo Ń Ṣe Ohun Tí Ó Wù Ú”
17. Ọwọ́ wo ni Jésù fi mú ṣíṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀, síbẹ̀ kí làwọn kan lè sọ?
17 Ìgbọràn kọjá kéèyàn máa sá fún ẹ̀ṣẹ̀; Kristi pa gbogbo àṣẹ tí Bàbá rẹ̀ pa fún un mọ́. Ó sọ pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” (Jòhánù 8:29) Ìgbọràn yìí máa ń fún Jésù ní ayọ̀ tó pọ̀ jaburata. Àmọ́, àwọn kan lè sọ pé ìgbọràn ò lè fi bẹ́ẹ̀ nira fún Jésù. Wọ́n lè máa rò pé Jèhófà nìkan ló ń gbọ́ràn sí lẹ́nu, Jèhófà sì rèé, ẹni pípé ni. Àmọ́, àwọn èèyàn aláìpé ló wà nípò àṣẹ táwa gbọ́dọ̀ gbọ́ tiwọn. Síbẹ̀, òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jésù ṣègbọràn sí àwọn èèyàn aláìpé tó wà nípò àṣẹ nígbà yẹn.
18. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ àpẹẹrẹ nínú jíjẹ́ onígbọràn nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́?
18 Ní gbogbo àkókò tí Jésù ṣì ń dàgbà, abẹ́ àṣẹ àwọn òbí rẹ̀, ìyẹn Jósẹ́fù àti Màríà, tí wọ́n jẹ́ aláìpé ló wà. Ó ṣeé ṣe kó ti rí ibi táwọn òbí rẹ̀ kù sí ju bí ọ̀pọ̀ ọmọdé ṣe lè rí i lọ. Ǹjẹ́ ó ṣàìgbọràn, ṣó kọjá àyè rẹ̀ nínú ìdílé kó wá máa sọ fáwọn òbí rẹ̀ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bójú tó ìdílé wọn? Gbọ́ ohun tí Lúùkù 2:51 sọ nípa Jésù tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá péré nígbà yẹn, ó ní: “Ó sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn.” Àpẹẹrẹ àtàtà ni ìgbọràn Jésù jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tí wọ́n ń sapá láti máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ tó yẹ wọ́n fún wọn.—Éfésù 6:1, 2.
19, 20. (a) Ìṣòro tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ló kojú Jésù nípa jíjẹ́ onígbọràn sí ẹ̀dá èèyàn aláìpé? (b) Kí nìdí táwọn Kristẹni tòótọ́ òde òní fi ní láti jẹ́ onígbọràn sáwọn tó ń múpò iwájú láàárín wọn?
19 Bó bá di pé kéèyàn ṣègbọràn sí èèyàn aláìpé, kò sẹ́nì kankan nínú àwa Kristẹni tòótọ́ tójú ẹ̀ rí nǹkan tójú Jésù rí. Ìwọ wo bí nǹkan ṣe yàtọ̀ tó lákòókò tó wá sáyé yẹn. Ó pẹ́ tí Jèhófà ti ń lo ètò ìjọsìn àwọn Júù tòun ti tẹ́ńpìlì rẹ̀ tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti ipò àlùfáà rẹ̀, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àkókò tí Jèhófà fẹ́ fi ìjọ Kristẹni rọ́pò rẹ̀. (Mátíù 23:33-38) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ẹ̀kọ́ èké látinú ìmọ̀ àwọn Gíríìkì lọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Ó tiẹ̀ burú débi pé ìwà jẹgúdújẹrá ti kúnnú tẹ́ńpìlì débi tí Jésù fi pè é ní “hòrò àwọn ọlọ́ṣà.” (Máàkù 11:17) Ǹjẹ́ Jésù ṣì máa ń lọ sínú tẹ́ńpìlì àti sínágọ́gù yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni! Jèhófà ṣì ń lo ìṣètò yẹn. Títí dìgbà tí Ọlọ́run fi dá sí ọ̀rọ̀ náà tó sì ṣe àtúnṣe tó yẹ, ṣe ni Jésù ń ṣègbọràn nípa lílọ síbi àjọyọ̀ ní tẹ́ńpìlì àti nínú sínágọ́gù.—Lúùkù 4:16; Jòhánù 5:1.
20 Bí Jésù bá lè ṣe ìgbọràn pẹ̀lú gbogbo ohun tójú ẹ̀ rí wọ̀nyẹn, àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ lónìí! Ó ṣe tán, sáà tiwa yìí yàtọ̀ gan-an ni, àkókò tá a wà yìí ni Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ tipẹ́ pé ìjọsìn mímọ́ á fìdí múlẹ̀. Ọlọ́run fi dá wa lójú pé òun ò ní gba Sátánì láyè láti sọ àwa èèyàn tóun tún rà padà di ẹlẹ́gbin. (Aísáyà 2:1, 2; 54:17) Òótọ́ ni pé à ń dojú kọ ẹ̀ṣẹ̀, a sì ń rí ipa tí àìpé ń ní lórí àwọn ará. Ṣùgbọ́n ṣó tọ́ ká tìtorí kùdìẹ̀ kudiẹ àwọn ẹlòmíì máa ṣàìgbọràn sí Jèhófà bóyá ká bẹ̀rẹ̀ sí í sá nípàdé tàbí ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe lámèyítọ́ àwọn alàgbà? Láé, a ò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀! Tọkàntọkàn ló yẹ ká máa ti àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ lẹ́yìn. Bá a bá jẹ́ onígbọràn, a óò máa lọ sípàdé àtàwọn àpéjọ, a ó sì máa tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tá à ń gbà.—Hébérù 10:24, 25; 13:17.
21. Báwo ni Jésù ṣe ṣe nígbà táwọn èèyàn fẹ́ mú kó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, àpẹẹrẹ wo nìyẹn sì jẹ́ fún wa?
21 Jésù ò gbà káwọn èèyàn ṣí i lọ́wọ́ ṣíṣègbọràn sí Jèhófà, kódà kò gbà fún àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n rò pé àwọn fẹ́ ẹ fẹ́re pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pétérù gbìyànjú láti rọ Jésù Ọ̀gá rẹ̀ pé kò pọn dandan kó jìyà kó sì kú. Jésù jẹ́ kí Pétérù mọ̀ pé òun ò gba ìmọ̀ràn búburú tí Pétérù rò pé ó dáa tó ń gba òun pé kóun ṣàánú ara Òun. (Mátíù 16:21-23) Lónìí, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ ọgbọ́n tí wọ́n máa ń dá lórí ọ̀ràn àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí wọ́n rò pé àwọn fẹ́ wọn fẹ́re àmọ́ tí wọ́n lè fẹ́ mú kí wọ́n ṣàìgbọràn sáwọn òfin Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀. Bíi tàwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ọ̀rúndún kìíní, ohun táwa náà gbà ni pé: “àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.
Èrè Tó Wà Fẹ́ni Tó Bá Ṣègbọràn bíi ti Kristi
22. Ìbéèrè wo ni Jésù wá ìdáhùn sí, báwo ló sì ṣe ṣe é?
22 Àkókò tí wọ́n fẹ́ pa Jésù yẹn gan-an ló le jù fún un láti fi hàn pé onígbọràn lòun. Lọ́jọ́ burúkú yẹn, “ó kọ́ ìgbọràn” ní kíkún. Ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ ló mú ṣẹ, kì í ṣe tara rẹ̀. (Lúùkù 22:42) Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ tí kò kù síbì kankan lélẹ̀. (1 Tímótì 3:16) Òun ni Ọlọ́run fi dáhùn ìbéèrè tó wà nílẹ̀ látọdún gbọ́nhan. Ìbéèrè náà ni pé: Ṣé ẹ̀dá èèyàn pípé lè jẹ́ onígbọràn sí Jèhófà, kódà lójú àdánwò? Ádámù àti Éfà ti kùnà. Ẹ̀yìn èyí ni Jésù wá, tó gbé láyé, tó kú tó sì fi hàn pé ó ṣeé ṣe láti jẹ́ onígbọràn láìkù síbì kan. Ẹni tó tóbi jù lọ lọ́wọ́ Jèhófà nínú àwọn tó dá ló wá ìdáhùn tó rinlẹ̀ jù lọ sí ìbéèrè náà. Ó ṣègbọràn pẹ̀lú bó tiẹ̀ ṣe mọ̀ pé òun á jẹ palaba ìyà tí ẹ̀mí òun á sì bọ́.
23-25. (a) Báwo ni ìgbọràn ṣe tan mọ́ ìṣòtítọ́? Ṣàpèjúwe rẹ̀. (b) Kí la máa jíròrò ní orí tó kàn?
23 Téèyàn bá fẹ́ fi hàn pé òun jẹ́ olùṣòtítọ́ tàbí ẹni tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, ẹni náà ní láti jẹ́ onígbọràn. Nítorí pé Jésù jẹ́ onígbọràn, ó dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe gbogbo aráyé lóore. (Róòmù 5:19) Jèhófà san Jésù lẹ́san rere. Báwa náà bá ń ṣègbọràn sí Ọ̀gá wa Kristi, Jèhófà á san wá lẹ́san. Ṣíṣègbọràn sí Kristi ló máa jẹ́ ká ní “ìgbàlà àìnípẹ̀kun”!—Hébérù 5:9.
24 Síwájú sí i, ìṣòtítọ́ fúnra rẹ̀, ẹ̀san ni. Òwe 10:9 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń rìn nínú ìwà títọ́ yóò máa rìn nínú ààbò.” A lè fi ìṣòtítọ́ wé ilé aláruru tí wọ́n fi bíríkì tó dáa kọ́. Gbogbo ìgbà téèyàn bá ń ṣe ìgbọràn ló dà bí ẹyọ bíríkì kọ̀ọ̀kan. Ẹyọ bíríkì kọ̀ọ̀kan lè má jọjú, ṣùgbọ́n ẹyọ kọ̀ọ̀kan yẹn láyè tiẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá sì wá to ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pọ̀ tán, ilé aláruru tí wọ́n fi kọ́ á dúró sán-ún. Bá a bá kó gbogbo ìgbọràn tá a ṣe pa pọ̀, tá à ń tò ó lórí ara wọn lójoojúmọ́ yí po ọdọọdún, ilé ìṣòtítọ́ tá a máa tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ á gọntíọ.
25 Kéèyàn jẹ́ onígbọràn fún ìgbà pípẹ́ tún rán wa létí ànímọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ìfaradà. Bí Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú ọ̀nà tó gbà jẹ́ onífaradà la óò jíròrò ní orí tó kàn.